Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Ọlọ́run Ló Fa Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kọ́ ló fà ìjìyà! Ìyà kò sí lára ohun tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé. Àmọ́, tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run, wọ́n sì fẹ́ láti máa dá pinnu pé ohun kan ló dára tàbí ohun kan ló burú. Wọ́n kọ ẹ̀yìn sí Ọlọ́run wọ́n sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwa lónìí ń jìyà ohun burúkú tí wọ́n ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ́ ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kìí dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Ìpọ́njú lè bá ẹnikẹ́ni, títí kan àwọn tí Ọlọ́run ṣojú rere sí pàápàá.