Ohun tí Bíbélì sọ

Ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló darí ohun táwọn kọ sílẹ̀. Wo àwọn àpẹẹrẹ yìí:

  • Dáfídì Ọba: “Ẹ̀mí Jèhófà ni ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wà lórí ahọ́n mi.”—2 Sámúẹ́lì 23:1, 2.

  • Wòlíì Aísáyà: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹ̀gbẹ́ ọmọ ogun, wí.”—Aísáyà 22:15.

  • Àpọ́sítélì Jòhánù: “Ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un.”—Ìṣípayá 1:1.