Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Ní Ayé?

Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Ní Ayé?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti mú kí àlàáfíà wà ní ayé ló ń já sí pàbó, bí yóò sì ṣe máa rí nìyẹn torí pé:

  • Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ọlọ́run kò dá àwọn èèyàn wọn pé kí wọ́n máa ṣàkóso ara wọn, torí náà, àlàáfíà tí wọ́n bá jàjà ní kò ní wà pẹ́ títí.

  • Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:3, 4) Tá a bá tiẹ̀ rí lára àwọn olórí ìjọba èèyàn tó fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, wọ́n ò lè mú àwọn ohun tó ń fa ogun kúrò pátápátá.

  • Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1–4) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí la wà, àwọn ìwà tí àwọn èèyàn ń hù mú kó ṣòro láti ní àlàáfíà.

  • Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Wọ́n ti lé Èṣù, tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́rún, wá sí sàkáání ilẹ̀ ayé. Òun ló ń mú kí àwọn èèyàn máa hùwà ìkà bíi tiẹ̀. A kò lè ní àlàáfíà níwọ̀n ìgbà tó bá jẹ́ òun ṣì ni “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòhánù 12:31.

  • [Ìjọba Ọlọ́run] yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [tó ń ta ko Ọlọ́run] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba Ọlọ́run ló máa fún wa ní ohun táá tẹ́ wa lọ́rùn, ìyẹn àlàáfíà tí kò lópin kárí ayé, kì í ṣe ìjọba èèyàn.—Sáàmù 145:16.