Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìlera

Ìlera

Ohun Tó Máa Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I

Ohun márùn-ún tó o lè ṣe báyìí kí ìlera rẹ lè dára sí i

Bá A Ṣe Lè Dènà Àrùn

Ojoojúmọ́ ni àgọ́ ara wa ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn kòkòrò àrùn tá ò lè rí.

Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀​​—Ìlera àti Ìfaradà

Ṣé téèyàn bá ní àìlera, ó túmọ̀ sí pé èèyàn lè láyọ̀ mọ́ láé?

Àwọn Ọ̀dọ́ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìlera

Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣọ́ ohun tí wàá jẹ, kó o sì ṣeré ìmárale? Nínú fídíò yìí, àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n lè nílera tó dáa.

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Sanra Jù?

Ka ohun tí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe tí wọ́n ò fi sanra jù àti bí wọ́n ṣe dín bí wọ́n ṣe sanra kù.

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Eré Ìmárale Á Fi Máa Wù Mí Ṣe?

Wo àwọn àǹfààní mẹ́ta tó o máa rí tó o bá ń ṣe eré ìmárale déédéé àti ohun táá jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ṣe é.

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Màá Fi Máa Sùn Dáadáa?

Wo ohun táwọn ojúgbà rẹ kan ti ṣe kí wọ́n lè máa sùn dáadáa.

Bó O Ṣe Lè Fara Da Àìsàn

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?

Bẹ́ẹ̀ ni! Kọ́ nípa ohun mẹ́ta tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Ní Àìsàn Tó Ò Ń Bá Fínra? (Apá 1)

Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin sọ ohun tó ń jẹ́ kí wọ́n lè máa fara da àìsàn tó ń ṣe wọ́n, kínú wọn sì máa dùn.

Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Ní Àìsàn Tó Ò Ń Bá Fínra? (Apá 2)

Ka ìrírí táwọn ọ̀dọ́ kan tó ń ṣàìsàn tó le fẹnu ara wọn sọ nípa bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ fara da ohun tó ń ṣe wọ́n.

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 3)

Ohun táwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta sọ lè jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa fara dà á.

Bó O Ṣe Lè Fara Da Àìlera

Jèhófà ‘Ń Bá Mi Gbé Ẹrù Mi Lójoojúmọ́’

Kí ló mú kí arábìnrin kan ní Nàmíbíà máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó ti lé lógún ọdún, bó tiẹ̀ jẹ́ pé onírúurú àìlera ló ń bá a fínra?

Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìlera, Okun Inú Ń Gbé Mi Ró

Obìnrin kan tó wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ máa ń rí “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Oju Jairo—Mu Ko Le Sin Olorun

Inu Jairo maa n dun, igbesi aye re si nitumo laika pe arun inu opolo to le ju lo n ba a finra.

Sísin Ọlọ́run Ni Oògùn Àìsàn Rẹ̀!

Wọ́n bí Onesmus pẹ̀lú àìsàn osteogenesis imperfecta tí kì í jẹ́ kí egungun lágbára. Báwo ni àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe tó wà nínú Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́?

Ọwọ́ Ni Mo Fi Ń Ṣe Gbogbo Nǹkan

Wọ́n bí James Ryan ní afọ́jú, nígbà tó yá, ó di adití. Kí ló mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀?

Fídíò Kékeré: “Ọpẹ́lọpẹ́ Rẹ̀ Lára Mi”

Wo fídíò yìí tó dá lórí ọkùnrin afọ́jú kan tó jàǹfààní nínú Bíbélì tí wọ́n ṣe fún àwọn afọ́jú.

Jèhófà Fi Àánú Hàn Sí Mi Ju Bí Mo Ṣe Rò Lọ

Félix Alarcón rí nǹkan gidi fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe lẹ́yìn tí ìjàǹbá alùpùpù mú kó rọ lápá àtẹsẹ̀.

Ìtọ́jú

Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Ọmọ Yín Bá Jẹ́ Abirùn

Jẹ́ ká wo àwọn ìṣòro mẹ́ta tó sábà máa ń jẹ yọ àti bí ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ṣe lè mú kó o borí wọn.

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Òbí Mi Bá Ń Ṣàìsàn?

Ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí. Wo ohun tó ran àwọn méjì lọ́wọ́.

Tí Àìsàn Gbẹ̀mí-Gbẹ̀mí Bá Ń Ṣe Ẹni Tá A Nífẹ̀ẹ́

Báwo làwọn mọ̀lẹ́bí ṣe lè ṣaájò ẹni tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ń ṣe kí wọ́n sì tù wọ́n nínú? Báwo lẹni tó ń tọ́jú aláìsàn náà ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn tí wọ́n máa ní láàárín àkókò náà?

Ààrùn àti Ìṣòro

Oúnjẹ Tó Gbòdì Lára Àtèyí Tí Kò Báni Lára Mu—Ṣó Yàtọ̀ Síra?

Ewu wo ló wà nínú kéèyàn fúnra rẹ̀ pinnu èyí tó ń ṣe òun?

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà

O lè dáàbò bo ara rẹ tó o bá ń gbé níbi tí ẹ̀fọn pọ̀ sí, tàbí tó o bá fẹ́ lọ sí ìlú tí ẹ̀fọn pọ̀ sí.

Ìdààmú

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun tó máa ń fà ìdààmú ọkàn àti bá a ṣe lè mọ̀ pé òun ló ń ṣe ẹnì kan. Wo ohun tí àwọn òbí àtàwọn mí ì lè ṣe.

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ń Sorí Kọ́?

Àwọn àbá yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe kó o lè bọ́ nínú ẹ̀.

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìrẹ̀wẹ̀sì Ọkàn?

Àwọn ohun mẹ́ta kan wà tí Ọlọ́run máa ń fún wa ká lè fara da ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.

Ìdààmú àti Àìbalẹ̀ Ọkàn

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?

Àwọn ohun mẹ́fà tó máa jẹ́ kí àníyàn ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí kò sì ní pa ẹ́ lára.

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Àníyàn?

Ó jọ pé ara ìgbésí ayé àwa èèyàn ni ṣíṣe àníyàn jẹ́. Ǹjẹ́ a lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn?

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àníyàn

Àníyàn tó dáa lè ṣàǹfààní; àmọ́ èyí tí kò dáa lè fa ìpalára. Bó o ṣe lè kojú rẹ̀, kó o sì ṣàṣeyọrí?

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro: Ojúṣe Tó Ń Wọni Lọ́rùn

Tó o bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan, wàá dá ara rẹ lágara. Kí lo lè ṣe tí àwọn ojúṣe rẹ kò fi ní wọ̀ ẹ́ lọ́rùn?

Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Mo Máa Ń Fẹ́ Ṣe Láìṣe Àṣìṣe Kankan?

Báwo lo ṣe lè fìyàtọ̀ sáàárín kó o máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ẹ àti kó o máa lé ohun tí ọwọ́ ẹ̀ ò lè tẹ̀?

Ohun tó o lè ṣe tí àyípadà bá ṣẹlẹ̀

Ìyípadà gbọ́dọ̀ wáyé. Wo ohun tí àwọn kan ti ṣe láti fara dà á.

Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan

Ohun mẹ́ta tó o lè ṣe láti níyì lójú ara wa.

Ìtọ́jú Ìlera

Ṣé Kristẹni Lè Gba Ìtọ́jú Lọ́dọ̀ Àwọn Dókítà?

Ǹjẹ́ irú ìtọ́jú tá a pinnu láti gbà ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run?

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Èèyàn Rẹ Bá Ń Ṣàìsàn

Ìdààmú máa ń bá ẹnì tó bá lọ rí dókítà tàbí tí wọ́n dá dúró sí ilé ìwòsàn. Báwo lo ṣe lè ran èèyàn rẹ tó wà nírú ipò yìí lọ́wọ́?