Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ

Wo fídíò nípa àwọn ọ̀dọ́ yíká ayé. Wọ́n sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ àti bí wọ́n ṣe ń borí wọn.

 

Kíka Bíbélì

Ìwé kíkà kì í fìgbà gbogbo rọrùn, àmọ́ téèyàn bá ń ka Bíbélì, ó lérè. Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin ṣàlàyé àǹfààní tí wọ́n ń rí bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì.

Ọlọ́run Wà Lóòótọ́

Àwọn ọ̀dọ́ kan sọ ohun tó jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà lóòótọ́ nínu fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta yìí.

Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ

Ṣé o fẹ́ káyé ẹ nítumọ̀? Gbọ́ bí Cameron ṣe ń sọ bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó ní ibi tí kò lérò.

Owó

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè fowó pa mọ́, bó ṣe yẹ kó o ná an àti bó ò ṣe ní sọ ara rẹ di ẹrú owó.

Ìlera

Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣọ́ ohun tí wàá jẹ, kó o sì ṣeré ìmárale? Nínú fídíò yìí, àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n lè nílera tó dáa.

Fífi Nǹkan Falẹ̀

Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ sọ nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa fi nǹkan falẹ̀ àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa jára mọ́ ohun tó ní í ṣe.

Fóònù

Fóònù ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi máa ń mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ní fóònù, ewu wo ló sì wà níbẹ̀?