Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Eré Ìmárale Á Fi Máa Wù Mí Ṣe?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Eré Ìmárale Á Fi Máa Wù Mí Ṣe?

Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní.” (1 Tímótì 4:8) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó máa ń sọ pé, “ó yẹ kí n máa ṣe eré ìmárale” ni kì í yá lára láti máa ṣe é lọ tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀.

  • “Nígbà tí mo wà ní ilé ìwé girama, ó máa ń yà mí lẹ́nu gan-an pé ọ̀pọ̀ ọmọ ilé ìwé ni kì í ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ eré ìmárale. Kò sì sí nǹkan tó le nínú ẹ̀ o, àfi bí ẹni fi àkàrà jẹ̀kọ!”—Richard, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

  • “Àwọn kan rò pé, ‘Kò yẹ kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sáré kiri nínú oòrùn títí táá fi rẹ̀ ẹ́, kó wá máa làágùn yọ̀bọ̀ torí pé ó fẹ́ ṣeré ìmárale, nígbà téèyàn lè máa lo géèmù orí kọ̀ǹpútà láti fi ṣe bí ẹni pé òun lòun ń sáré kiri.’”—Ruth, ẹni ọdún méjìlélógún [22].

Tó bá jẹ́ pé ohun tíwọ náà ń rò nìyẹn, wo àwọn àǹfààní mẹ́ta tó o máa rí tó o bá ń ṣe eré ìmárale déédéé.

Àǹfààní àkọ́kọ́. Eré ìmárale máa jẹ́ kí àwọn èròjà tó ń dènà àrùn nínú ara rẹ túbọ̀ lágbára. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Bàbá mi máa ń sọ pé, ‘Bí o kò bá ráyè eré ìmárale, àìsàn tó máa gba àyè yẹn lò ń kọ̀wé sí o.’

Àǹfààní kejì. Eré ìmárale máa ń jẹ́ kí ọpọlọ tú àwọn èròjà kan jáde sínú ara, èyí tó máa ń jẹ́ kí ara ẹni balẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Emily sọ pé: “Bí ọ̀pọ̀ nǹkan bá ń da ọkàn mi láàmú, bí mo bá ti sáré báyìí, ńṣe ni ọkàn mi máa ń fúyẹ́. Ó máa ń jẹ́ kí ara tù mí, ọkàn mi á sì tún balẹ̀.

Àǹfààní kẹta. Eré ìmárale máa jẹ́ kó o lè dára yá. Ọmọ ọdún méjìlélógún [22] kan tó ń jẹ́ Ruth sọ pé, “Mo fẹ́ràn kí n máa ṣe eré ìdárayá ní ìta gbangba, irú bíi rírìn lọ síbi tó jìn díẹ̀, lílúwẹ̀ẹ́, gígun àpáta, ṣíṣeré lórí yìnyín àti gígun kẹ̀kẹ́.

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Ó kéré tán, máa fi ogún [20] ìṣẹ́jú ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn kan tó o fẹ́ràn lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀.

Máa rántí pé: Òótọ́ ni pé èèyàn lè jogún àìlera látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹni, síbẹ̀, àwọn nǹkan tó o bá ń ṣe ló sábà máa ń pinnu bí ìlera rẹ ṣe máa rí. Torí náà tó o bá sọ pé “ó yẹ kí n máa ṣe eré ìmárale,” ọwọ́ ẹ ló kù sí; o sì lè ṣe ohun tó wù ẹ́ nípa rẹ̀!