Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Tó bá jẹ́ pé o kì í sùn dáadáa, o ò ní lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ kó o ṣe é!

  • “Bí mi ò bá sùn dáadáa, wàhálà dé nìyẹn. Mi ò ní lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí mo bá ń ṣe!”​—Rachel, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].

  • “Bó bá ti ń di nǹkan bí aago méjì ọ̀sán, ó máa ń rẹ̀ mí gan-an débi pé mo lè sùn lọ níbi tí mo bá ti ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀!”​—Kristine, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].

Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé o kì í sùn tó bó ṣe yẹ? Wo ohun táwọn ojúgbà rẹ kan ti ṣe.

Máa tètè sùn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Catherine sọ pé: “Mo máa ń rí i dájú pé mi kì í pẹ́ kí n tó sùn.

Má ṣe máa rojọ́ lóru. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ́ Richard sọ pé: “Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń pè mí lóru tàbí kí wọ́n fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi, ohun tí mo wá ń ṣe báyìí ni pé, mo máa ń tètè sọ fún wọn pé mo fẹ́ sùn, màá sì lọ sùn.

Yan àkókò pàtó tí wàá máa sùn àti ìgbà tí wàá máa jí. Ọmọ ogún [20] ọdún kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé: “Ní báyìí, mo máa ń gbìyànjú láti rí i pé mi ò jẹ́ kí àkókò tí mò ń sùn àti àkókò tí mò ń jí lójoojúmọ́ yẹ̀.

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Rí i pé, ó kéré tán, ò ń sun oorun wákàtí mẹ́jọ ní òru mọ́jú.

Ó máa jàǹfààní gan-an tó o bá ń ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kó o sùn dáadáa. Rántí pé bí ara rẹ bá le dáadáa, ìrísí rẹ á túbọ̀ dára, ara rẹ á dá ṣáṣá, ọpọlọ rẹ á sì jí pépé.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tí kò sí ohun tó o lè ṣe nípa rẹ̀, rántí pé dé ìwọ̀n àyè kan, o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìrísí rẹ àti ìlera rẹ rí. Erin tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Tá a bá ní ká wò ó, ọwọ́ ìwọ fúnra rẹ gan-an lọ̀rọ̀ ìlera rẹ wà.