Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?

Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
  • Kí ló túmọ̀ sí pé kẹ́ni méjì máa fẹ́ra?

  • Kí ló yẹ kó jẹ́ ìdí táwọn méjì fi ń fẹ́ra?

  • Ṣé mo ti dàgbà tó láti lẹ́ni tí mò ń fẹ́?

  • Kí nìdí tó fi dáa kí n ní sùúrù kí n tó lẹ́ni tí mò ń fẹ́?

Kí ló túmọ̀ sí pé kẹ́ni méjì máa fẹ́ra?

  • Bí ìgbín bá fà, ìkarahun a tẹ̀ lé e lọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹnì kan tí kì i ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Ṣé ẹ ti ń fẹ́ra yín nìyẹn?

  • Ìwọ àti ẹnì kan tí kì i ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ fẹ́ràn ara yín gan-an. Ọ̀pọ̀ ìgbà lo máa ń pe ẹni yìí lórí fóònù lójúmọ́ tàbí kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i. Ṣé ẹ ti ń fẹ́ra yín nìyẹn?

  • Gbogbo ìgbà tíwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ṣe fàájì, ẹnì kan wà tí kì i ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ tíwọ àti ẹ̀ sábà máa ń dá sọ̀rọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ṣé ẹ ti ń fẹ́ra yín nìyẹn?

Ó lè má ṣòro fún ẹ láti dáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó o ti kọ́kọ́ rò ó díẹ̀ kó o tó dáhùn ìbéèrè kejì àti ìkẹta. Kí túmọ̀ sí gan-an pé kẹ́ni méjì máa fẹ́ra?

Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ́, tí ohunkóhun bá ti ń pa ìwọ àti ẹnì kan pọ̀, tọ́kàn rẹ ń fà sí onítọ̀hún, tọ́kàn tónítọ̀hún náà sì ń fà sí ẹ, ẹ ti ń fẹ́ra yín nìyẹn.

Torí náà, bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́ta yẹn. Tọ́rọ̀ ìwọ àti ẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ bá ti kọjá ọ̀rẹ́ lásán, tọ́kàn yín ti ń fà síra yín, tẹ́ ẹ sì jọ ń sọ̀rọ̀ déédéé, ì báà jẹ́ lórí fóònù tàbí lójúkojú, ní gbangba tàbí kọ̀rọ̀, ẹ ti ń fẹ́ra nìyẹn.

Kí ló yẹ kó jẹ́ ìdí táwọn méjì fi ń fẹ́ra?

Ó yẹ káwọn tó bá ń fẹ́ra sọ́nà ní ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni pé kí wọ́n lè mọ̀ bóyá àwọn méjèèjì á bára wọn kalẹ́ tí wọ́n bá fẹ́ra sílé.

Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀dọ́ kan ò ka kí ọkùnrin àti obìnrin máa fẹ́ra sí nǹkan bàbàrà. Ó lè jẹ́ pé ó kàn wù wọ́n láti máa wà lọ́dọ̀ ẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn láì ní in lọ́kàn láti fẹ́ onítọ̀hún. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa firú ẹni bẹ́ẹ̀ gbayì láwùjọ tàbí kí wọ́n máa fi ṣe fọ́rífọ́rí pé àwọn náà ti tẹ́gbẹ́.

Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Heather sọ pé, “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kì í fẹ́ra ju ọ̀sẹ̀ kan sí méjì tí wọ́n fi máa ń tú ká. Wọ́n ti sọ àjọṣe àárín wọn di ọsàn téèyàn lè mu kó sì sọ nù tó bá ti sú u, wọn ò mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn lè bá wọn dàgbà, kó sì tú ìgbéyàwó wọn ká lọ́jọ́ iwájú.”

Òótọ́ kan ni pé, tíwọ àti ẹnì kan bá ń fẹ́ra, ohun tó o bá ń ṣe á máa nípa lórí onítọ̀hún. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kó o mohun tó ò ń ṣe, kó máà jẹ́ pé ṣe lo kàn ń mú ẹni náà ṣeré.—Lúùkù 6:31.

Tó o bá ń fẹ́ ẹnì kan, àmọ́ tó ò ní in lọ́kàn láti fi ṣe ọkọ tàbí ìyàwó ẹ, ńṣe lo dà bí ọmọdé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra bèbí, tó wá ń fi ṣeré, àmọ́ tó wábi jù ú sí nígbà tó yá

Rò ó wò ná: Ṣó máa wù ẹ́ kí ẹnì kan máa mú ẹ ṣeré bí ẹni ń fi bèbí ọmọdé ṣeré fúngbà díẹ̀, tó wá jù ú síbì kan? Ìwọ náà, má ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹlòmíì! Bíbélì sọ pé ìfẹ́ “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Chelsea sọ pé: “Nígbà míì, mo máa ń rò ó pé kéèyàn lẹ́ni tó ń fẹ́ ò ju ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré lọ, àmọ́ tẹ́nì kan bá ti ń ronú ìgbéyàwó, tẹ́nì kejì ò sì ríyẹn rò, ó ti kúrò lọ́rọ̀ eré.”

Ìmọ̀ràn: Tó o bá fẹ́ múra sílẹ̀ de ìgbà tó o máa ní àfẹ́sọ́nà tàbí tó o máa ṣègbéyàwó, ka 2 Pétérù 1:5-7, kó o sì yan ànímọ́ kan tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí. Lẹ́yìn oṣù kan, ṣàyẹ̀wò bó o ṣe mọ ànímọ́ yẹn tó, kó o sì wò ó bóyá ó ti ń hàn nínú ìwà ẹ.

Ṣé mo ti dàgbà tó láti lẹ́ni tí mò ń fẹ́?

  •  Ọmọ ọdún mélòó lo rò pé ó yẹ kéèyàn tó kó tó lẹ́ni tó ń fẹ́?

  •  Wá bi Dádì tàbí Mọ́mì ẹ ní ìbéèrè yìí.

Ó ṣeé ṣe kí ohun tó o sọ yàtọ̀ sí tòbí ẹ. Ó sì lè má yàtọ̀! Ìwọ náà lè wà lára àwọn ọ̀dọ́ tó gbọ́n, tí wọ́n pinnu pé àwọn máa fẹ́ dàgbà sí i kí wọ́n lè mọ ẹni tí wọ́n fẹ́ fẹ́ sọ́nà dáadáa.

Ohun tí Danielle tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún pinnu pé òun máa ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Bí nǹkan ṣe máa ń rí lára mi lọ́dún méjì sẹ́yìn ti yàtọ̀ sí báyìí. Ohun tó máa ń wù mí lára ọkùnrin nígbà yẹn ti yàtọ̀ sí ìsinyìí. Ní báyìí gan-an, mi ò rò pé mo tíì lè ṣe ìpinnu yẹn. Mo fẹ́ ní sùúrù ọdún mélòó kan, tí mo bá ti mọ ohun tí mo fẹ́ lára ọkùnrin dáadáa, mo wá lè máa rò ó pé mo fẹ́ ní àfẹ́sọ́nà.”

Ìdí míì tún wà tó fi bọ́gbọ́n mu pé kó o ní sùúrù díẹ̀. Bíbélì fi ọ̀rọ̀ náà, “ìgbà ìtànná òdòdó èwe” ṣàpèjúwe ìgbà kan nígbèésí ayé ẹni téèyàn máa ń fẹ́ ní ìbálòpọ̀ ṣáá, tó sì máa ń wuni gan-an láti máa fara ro ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèèyàn. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Tó o bá ti wá lọ lẹ́ni tó ò ń fẹ́ nígbà tí nǹkan ṣì ń rí báyìí lára rẹ, ó lè rúná sí ọ̀rọ̀ náà, kó sì mú kó o ṣèṣekúṣe.

Ìyẹn lè máà jẹ́ nǹkan bàbàrà lójú àwọn ojúgbà ẹ torí ọ̀pọ̀ nínú wọn ló máa ń fẹ́ tètè mọ bí ìbálòpọ̀ ṣe ń rí. Àmọ́ kò yẹ kíwọ máa ronú lọ́nà yẹn! (Róòmù 12:2) O ṣáà mọ̀ pé Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o “sá fún ìṣekúṣe.” (1 Kọ́ríńtì 6:18, Bíbélì New International Version) Tó o bá ní sùúrù dìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ ò bá gbà ẹ́ lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ mọ́, wàá lè “mú ibi kúrò ní ara rẹ.”—Oníwàásù 11:10, Bíbélì Mímọ́.

Kí nìdí tó fi dáa kí n ní sùúrù kí n tó lẹ́ni tí mò ń fẹ́?

Tó bá ń wù ẹ́ láti lẹ́ni tó ò ń fẹ́ láì tíì ṣe tán àti ṣègbéyàwó, ṣe lọ̀rọ̀ ẹ máa dà bí ìgbà tó o fẹ́ fi agídí ṣèdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama nígbà tó o ṣì wà níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ìwọ náà rí i pé kò bọ́ sí i! Àfi kó o kọ́kọ́ mọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni níléèwé girama, kó o lè mọ ohun tó o máa bá pàdé nínú ìdánwò ọ̀hún.

Bí ọ̀rọ̀ fífẹ́ra sọ́nà ṣe rí gan-an nìyẹn.

Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré. Torí náà, kó o tó tọrùn bọ̀ ọ́, ó ṣe pàtàkì kó o kọ́kọ́ fara balẹ̀ mọ béèyàn ṣe ń báni dọ́rẹ̀ẹ́,.

Tó bá sì yá, tó o rẹ́ni tó tẹ́ ẹ lọ́rùn, wàá lè mọ bí wàá ṣe máa ṣe sí i kẹ́ ẹ lè mọwọ́ ara, kẹ́ ẹ sì dọ̀rẹ́ ara yín. Ó ṣe tán, tí tọkọtaya bá jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn, ìgbéyàwó wọn á dùn bí oyin.

Má rò ó pé tó ò bá tíì lẹ́ni tó ò ń fẹ́, o ò ní lómìnira. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìgbà yẹn gan-an lo máa lómìnira tó pọ̀ jù láti ‘yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.’ (Oníwàásù 11:9) Wàá tún ráyè tún ìwà ẹ ṣe. Pàtàkì ibẹ̀ ni pé wàá lè mú kí àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run dáa sí i.—Ìdárò 3:27.

Ní báyìí ná, o láwọn ọ̀rẹ́ tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Àmọ́ báwo ló ṣe yẹ kó o máa ṣe pẹ̀lú wọn? Ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ jọ wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ lọ́kùnrin lóbìnrin, káwọn àgbàlagbà sì wà níbi tẹ́ ẹ wà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tammy sọ pé: “Ó máa ń dáa kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀. Ìyẹn gan-an ló máa ń dùn jù.” Monica náà gbà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Ó dáa gan-an kéèyàn máa wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀, torí wàá mọ oríṣiríṣi èèyàn tí ànímọ́ wọn yàtọ̀ síra.”

Àmọ́, tó o bá ti lọ kánjú lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ó ṣeé ṣe kó o kó ẹ̀dùn ọkàn bá ara ẹ. Torí náà, fara balẹ̀, má kánjú. Fi àsìkò tó o wà yìí kọ́ béèyàn ṣe ń yan ọ̀rẹ́, tí àárín yín á sì gún. Tó bá wá yá, tó wù ẹ́ láti ní ẹni tó ò ń fẹ́, wàá ti mọ ara ẹ dáadáa, wàá sì ti mọ ohun tó o fẹ́ gan-an lára ẹni tó o máa fẹ́ fi ṣe ọkọ tàbí ìyàwó.