Gbogbo ìgbà lo máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Àmọ́ o rí i pé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ọ̀kan wà nínú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tọ́rọ̀ yín ti wá wọ̀ gan-an. Ìṣòro ibẹ̀ kàn ni pé, ọ̀rẹ́ ẹ yìí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. O lè máa rò ó pé ‘Ọ̀rẹ́ lásán ni wá,’ kó o sì máa wò ó pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ń ṣe òun náà. Ṣé nǹkan bàbàrà ni?

 Ohun tó lè ṣẹlẹ̀

Kò sóhun tó burú nínú kó o lọ́rẹ̀ẹ́ tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó o bá ń nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí ẹni kan jú àwọn tó kù? Ẹni náà lè máa rò ó pé o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kọjá ti ọ̀rẹ́ lásán.

Àmọ́ ṣé ohun tó wà lọ́kàn tìẹ nìyẹn? Jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà tí èyí lè gbà ṣẹlẹ̀ láì fura.

 • Ẹnì kan ló máa ń fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà.

  “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè pinnu bọ́rọ̀ ṣe máa rí lára ẹnì kan, kò ní dáa kó o máa pa kún un. Bí àpẹẹrẹ, o sọ pé ọ̀rẹ́ lásán ni yín, o wá ń pe onítọ̀hún ní gbogbo ìgbà, ẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ ṣáá. Bí ẹni da epo síná ló rí.”—Sierra.

 • O máa ń gbà kí ẹnì kan máa bá ẹ sọ̀rọ̀.

  “Ọmọbìnrin kan sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù, òun ló máa ń bẹ̀rẹ̀ ẹ̀, kì í ṣe èmi. Àmọ́ gbogbo ìgbà ni mo máa ń fèsì ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wá mú kó ṣòro fún mi láti jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rẹ́ lásán ni wá.”—Richard.

 • O máa ń fẹ́ kí ẹnì kan máa bá ẹ sọ̀rọ̀.

  “Ọ̀pọ̀ ló rò pé kò sóhun tó burú nínú títage. Ṣe ni wọ́n máa ń mú àwọn míì ṣeré, wọn ò ní in lọ́kàn láti fẹ́ wọn. Irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa, ó sì máa ń pa àwọn ẹlòmíì lára.”—Tamara.

Òótọ́ ibẹ̀: Téèyàn bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ṣáá, tó sì ń pe àfíyèsí àrà ọ̀tọ̀ sẹ́ni náà, ó lè mú kí ẹni náà máa rò pé ẹ kì í ṣe ọ̀rẹ́ lásán.

 Ìdí tó fi ṣe pàtàkì

 • Ó máa ń pa ẹnì kejì lára.

  Ohun tí Bíbélì sọ: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Kí lo máa wá sí ẹ lọ́kàn tí ẹnì kan bá ń fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí ?

  Ó dà bí ìgbà tó o bá fi ìwọ̀ mú ẹja, àmọ́ o ò mú ẹja náà kúrò lẹ́nu ìwọ̀, bẹ́ẹ̀ lo ò tú u sílẹ̀. Irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àti ẹlòmíì. Tó o bá mọ̀ pé o ò lẹ́nì kan fẹ́, àmọ́ tẹ́ ẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ ṣáá, tó ò yé pè é, ó máa pa dà pa ẹni yẹn lára.”—Jessica .

 • Ó lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́.

  Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Irú ẹni wo lo máa ka ẹni tó jẹ́ pé tara ẹ̀ nìkan ló mọ̀ sí? Ojú wo làwọn èèyàn á fi máa wo ẹni náà?

  “Mi ò gba ti ọkùnrin tó máa ń bá àwọn obìnrin tage. Tí ẹni tó máa ń bá obìnrin tage bá sì gbéyàwó lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kó dalẹ̀ ìyàwó rẹ̀. Tara wọn nìkan ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀, torí ṣe ni wọ́n máa ń fi àwọn ẹlòmíì gborúkọ.”—Julia.

Òótọ́ ibẹ̀: Ṣe ni ẹni tó bá ń fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sẹ́lòmíì láìní in lọ́kàn láti fẹ́ onítọ̀hún ń pa ara rẹ̀ àti ẹlòmíì lára.

 Ohun tó o lè ṣe

 • Bíbélì sọ pé ká máa ṣe “àwọn ọ̀dọ́kùnrin gẹ́gẹ́ bí arákùnrin” àti “àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.” (1 Tímótì 5:1, 2) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà yẹn, kò ní jẹ́ kí ọ̀rẹ́ tó ò ń bá àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ṣe dà rú.

  “Ká sọ pé mo ti lọ́kọ, mi ò ní máa bá ọkọ ẹlòmíì tage. Mo ti ń fi kọ́ra báyìí tí mi ò tíì lọ ilé ọkọ, mo máa ń ṣọ́ra ṣe pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, ó sì dáa bẹ́ẹ̀.”—Leah.

 • Bíbélì sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá.” (Òwe 10:19) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ sísọ nìkan ni ìlànà yẹn bá wí, ó tún kan fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, títí kan bó o ṣe ń fi ránṣẹ́ tó àti ohun tó ò ń bá ẹni náà sọ.

  “Kò sídìí tó fi yẹ kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ọmọbìnrin kan lójoojúmọ́ nígbà tó ò ní in lọ́kan láti fẹ́ ẹ.”—Brian.

 • Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà.” (Jákọ́bù 3:17) O bọ ẹnì kan lọ́wọ́ lọ́nà tí ò ní túmọ̀ sí nǹkan kan, o sì lè ṣe é lọ́nà tí ẹni tó o bọ̀ lọ́wọ́ á fi máa ro nǹkan míì.

  “Mo máa ń bá àwọn èèyàn ṣeré, àmọ́ mo máa ń ṣe é níwọ̀n, mi kì í kọjá àyè mi.”—Maria.

Òótọ́ ibẹ̀: Máa ṣọ́ra ṣe pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé, “Kò rọrùn láti rí ọ̀rẹ́ tòótọ́, tó o bá wá jàjà rí, máa ṣọ́ra ṣe pẹ̀lú wọn kó o má bàa lọ mú kí wọ́n máa ro nǹkan míì, torí ìyẹn lè ba ọ̀rẹ́ yín jẹ́.”

 Àbá

 •  Má ṣe kó ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì dà nù. Tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé, “Ṣé ìwọ àti lágbájá ń fẹ́ra ni?” ó lè jẹ́ pé ẹ ti sún mọ́ra jù nìyẹn.

 •  Ọwọ́ kan náà ni kó o fi mú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Má yan ẹnì kan láàyò, kó o máa wá bá òun nìkan sọ̀rọ̀ ṣáá.

 • Má ṣe máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ ní gbogbo ìgbà, máa ṣọ́ ohun tó ò ń fi ránṣẹ́, kó o sì máa ṣọ́ ìgbà tí wàá fi ránṣẹ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Alyssa sọ pé, “Kò yẹ kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lóru.”