Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán Ni Wá àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Wọ̀ Ọ́?—Apá 1: Báwo Ni Ẹni Yìí Ṣe Ń Ṣe sí Mi?

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán Ni Wá àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Wọ̀ Ọ́?—Apá 1: Báwo Ni Ẹni Yìí Ṣe Ń Ṣe sí Mi?

Ṣé ẹnì kan wà tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ tó o fẹ́ràn gan-an? Ó tiẹ̀ lè dá ẹ lójú pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ń ṣe òun náà. Gbogbo ìgbà lẹ kúkú máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara yín, ẹ sábà máa ń wà pa pọ̀ níbi àpèjẹ . . . , ó sì ṣe kedere pé nígbà míì, ẹni náà máa ń bá ẹ tage.

Lo wá ní kó o bi í nípa bẹ́ ẹ ṣe jẹ́ sí ara yín, kó o lè mọ̀ bóyá bákan náà ló ṣe ń ṣe ẹ̀yin méjèèjì. Ló bá sọ fún ẹ pé, “Ọ̀rẹ́ lásán ni wá, kò sí nǹkan kan láàárín wa.”

  • Bó ṣe máa ń rí lára ẹni

  • Ohun tó máa ń fà á

  • Ohun tó o lè ṣe

Bó ṣe máa ń rí lára ẹni

“Ṣe ni orí mi kanrin, inú ẹ̀ bí mi gan-an, inú bí mi sí ara mi! Ojoojúmọ́ la máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara wa, ó sì gba tèmi gan-an. Bọ́rọ̀ ìfẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́kàn mi nìyẹn.”—Jasmine.

“Èmi àti ọmọbìnrin yìí máa ń sin àwọn kan tó fẹ́ra wọn sọ́nà jáde kí wọ́n má bàa dá wà. Ohun tó máa ń jọ nígbà míì ni pé àwa méjèèjì ń fẹ́ra sọ́nà, a wá bá àwọn méjì míì tó ń fẹ́ra sọ́nà jáde. Àwa méjèèjì máa ń sọ̀rọ̀ gan-an, nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra léraléra. Bí àlá ló rí nígbà tó sọ fún mi pé ọ̀rẹ́ lásán lòun kà mí sí, tí mo sì wá mọ̀ pé ó ti lẹ́ni tó ń fẹ́.”—Richard.

“Ọmọkùnrin kan máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lójoojúmọ́, ìgbà míì sì wà tá a máa ń bára wa tage. Àmọ́ nígbà tí mo sọ fún un bó ṣe ń ṣe mí, pé ìfẹ́ ẹ̀ ti gbilẹ̀ lọ́kàn mi, ló bá bú sẹ́rìn-ín, ó ní, ‘Mi ò tíì ṣe tán láti ní ẹnì kankan tí mò ń fẹ́ báyìí o!’ Mo sunkún, ojú mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ.”—Tamara.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá rò pé ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹnì kan ti wọ̀, àmọ́ nígbà tó yá, tó o rí i pé kì í ṣe bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ń ṣe onítọ̀hún, ó lè múnú bí ẹ lóòótọ́, ó lè dójú tì ẹ́ tàbí kó o máa rò ó pé ẹni náà ti dà ẹ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé, “Inú mi bà jẹ́ nígbà tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi, ọ̀rọ̀ náà dùn mí gan-an. Ó ṣe díẹ̀ kí n tó tún fọkàn tán ẹnikẹ́ni.”

Ohun tó máa ń fà á

Ó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tó jẹ́ pé ọ̀rẹ́ lásán ló kà ẹ́ sí tẹ́ ẹ bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara yín tàbí tí ẹ̀ ń bá ara yín sọ̀rọ̀ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Wo ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ.

“Ẹnì kan lè fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ torí pé ọwọ́ ẹ̀ dilẹ̀, àmọ́ ìwọ lè rò pé onítọ̀hún ti ń gba tìẹ. Tó bá sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, o lè wá máa rò ó pé ó ti yófẹ̀ẹ́ rẹ.”—Jennifer.

“Ó lè wu ọ̀kan nínú wọn pé kí àwọn máa fẹ́ra, àmọ́ kó jẹ́ pé ṣe ni ẹnì kejì kàn ń wá ẹni táá máa bá sọ̀rọ̀, kó lè máa fi ẹ́ gborúkọ.”—James.

“Tẹ́nì kan bá fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ pé ‘ó dàárọ̀ o,’ ìwọ lè máa rò ó pé ó ti gba tìẹ gan-an ló ṣe fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ, nígbà tó sì jẹ́ pé onítọ̀hún kàn ń kí ẹ lásán ni.”—Hailey.

“Tẹ́nì kan bá fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹlòmíì, tó wá ya ojú bèbí sí i, ó lè túmọ̀ sí pé ṣe ló kàn ń bá onítọ̀hún ṣeré tàbí pé ó ń bá a tage. Nígbà míì, ẹni tó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lè rò pé ó ń bá òun tage.”—Alicia.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Má lọ rò pé ẹnì kan ti gba tìẹ torí pé ó máa ń bá ẹ sọ̀rọ̀.

O lè máa rò ó pé kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀, àbí? Òótọ́ ni! Bíbélì sọ pé: “Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó sì burú jáyì!” (Jeremáyà 17:9, Bíbélì Mímọ́) Ó lè mú kó o gbà lọ́kàn ẹ pé ẹnì kan ti yófẹ̀ẹ́ ẹ, àmọ́ kí ojú ẹ wálẹ̀ wọ̀ọ̀ tó o bá wá mọ̀ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ kọ́ ló ń ṣe ẹni náà.

Ohun tó o lè ṣe

  • Bá ara rẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tó wà láàárín ẹ̀yin méjèèjì. Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ó dá mi lójú pé bí ẹni yìí ṣe ń ṣe sí mi kọ́ ló ń ṣe sáwọn ẹlòmíì?’ Má ṣe jẹ́ kí ìmọ̀lára rẹ ru bò ẹ́ lójú débi tó ò ní lè lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ.Róòmù 12:1.

  • Máa fòye mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Àwọn nǹkan kan lè máa ṣẹlẹ̀ tó lè mú kó máa ṣe ẹ́ bíi pé ẹ kì í ṣe ọ̀rẹ́ lásán, àmọ́ rí i pé ò ń kíyè sí àwọn àmì tó lè mú kó o mọ̀ pé ọ̀rọ̀ lè má rí bẹ́ẹ̀. Má kàn rò pé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà ló ń ṣe ẹnì kejì.

  • Ní sùúrù. Tẹ́nì kan ò bá là á mọ́lẹ̀ pé òun fẹ́ kí ìwọ àti òun máa fẹ́ra, má ronú débẹ̀ nígbà tí kò tíì sọ ọ́ torí kó má bàa dùn ẹ́ jù tọ́rọ̀ ò bá pa dà rí bẹ́ẹ̀.

  • Má tan ara ẹ jẹ́. Bíbélì sọ pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá kì í ṣe ojú ọ̀rẹ́ lásán ni ẹnì kan fi ń wò ẹ́, kíwọ àti ẹni náà jọ sọ ọ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Valerie sọ pé, “Tó bá jẹ́ pé bákan náà kọ́ ló ń ṣe ẹ̀yin méjèèjì, ó dáa kẹ́ ẹ tètè mọ̀. Ó lè dùn ẹ́ díẹ̀ o, àmọ́ ó sàn ju kó jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù lo tó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ò tiẹ̀ sí lọ́kàn ẹnì kejì, ìyẹn ló máa dùn ẹ́ jù.”

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ,” bí Òwe 4:23 ṣe sọ. Tọ́kàn ẹ bá ń fà sí ẹnì kan, wádìí bóyá ọkàn onítọ̀hún náà ń fà sí ẹ. Tó o bá ti ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ ọkàn ẹ láìmọ̀ bóyá bẹ́ẹ̀ ló rí lọ́kàn ẹnì kejì, ṣe ló máa dà bí ẹni fẹ́ gbin igi sórí òkúta bọrọgidi.

Tó o bá rí i pé lóòótọ́ ni ẹni náà fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, tíwọ náà ti dàgbà tẹ́ni tó ń ní àfẹ́sọ́nà, tó o sì ti ṣe tán láti ní àfẹ́sọ́nà, ọwọ́ ẹ ló kù sí bóyá wà á fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Rántí pé ìgbéyàwó máa ṣàṣeyọrí tí tọkọtaya bá ní àfojúsùn kan náà nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run, tí wọn kì í fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún ara wọn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ síra wọn. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Kódà, ọ̀rẹ́ ni irú wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n tó fẹ́ra, okùn ọ̀rẹ́ wọn kì í sì í já kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣègbéyàwó.Òwe 5:18.