Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Máa Tage?

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Máa Tage?
 • Kí ló túmọ̀ sí kéèyàn máa tage?

 • Kí ló máa ń mú káwọn kan ṣe bẹ́ẹ̀?

 • Ewu wo ló wà níbẹ̀?

 • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí ló túmọ̀ sí kéèyàn máa tage?

Ohun táwọn kan rò ni pé téèyàn bá ń bá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ tage, ṣe ló ń dọ́gbọ́n jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó ń sọ tàbí bó ṣe ń ṣe sí i pé òun fẹ́ káwọn máa fẹ́ra. Ṣó burú kéèyàn jẹ́ kẹ́nì kan mọ̀ pé òun fẹ́ káwọn máa fẹ́ra? Kò sóhun tó burú níbẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ann sọ pé, “Tó bá ti tó kó o lẹ́ni tó ò ń fẹ́, tó o sì ti rí ẹni tó wù ẹ́, kò sọ́gbọ́n míì tó o lè dá tí wàá fi mọ̀ bóyá bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ń ṣe ẹnì kejì.”

Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ohun tá a máa sọ̀rọ̀ lé lórí ni kéèyàn máa bá ẹnì kan tage láìní in lọ́kàn pé òun fẹ́ kí òun àti onítọ̀hún máa fẹ́ra.

“Ọ̀tọ̀ ni kójú èèyàn wà lára ẹnì kan torí pé ó wù ẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni kéèyàn máa ṣe bíi pé òun fẹ́ kóun àti ẹnì kan máa fẹ́ra, bẹ́ẹ̀ kò ní in lọ́kàn. Ṣe lọ̀rọ̀ máa dà bí ẹni gbé èèyàn sórí àga ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta.”​—Deanna.

Kí ló máa ń mú káwọn kan ṣe bẹ́ẹ̀?

Ṣe làwọn kan máa ń tage torí kí wọ́n lè máa fi gba orúkọ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Hailey sọ pé, “Tó o bá ti ń rí i pé ò ń rí irú ẹ̀ ṣe, ó lè máa dùn mọ́ ẹ, kó o sì fẹ́ máa ṣe é lọ.”

Tó o bá ń mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kẹ́nì kan máa rò ó pé ó wù ẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, tíwọ ò sì ní in lọ́kàn láti fẹ́ ẹ, ó fi hàn pé o ò tiẹ̀ ro tẹ́nì kejì yẹn rárá, ó sì yẹ kó o ro orí ara ẹ wò. Bíbélì sọ pé: “Ìwà òmùgọ̀ jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀ lójú ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.”​—Òwe 15:21.

Ohun tí Hailey fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́gbọ́n mu, ó ní, “Téèyàn bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tage, ó lè dà bíi pé kò séwu, àmọ́ ibi tọ́rọ̀ sábà máa ń parí sí kì í dáa.”

Ewu wo ló wà níbẹ̀?

 • Tó o bá ń tage, ó máa bà ẹ́ lórúkọ jẹ́.

  “Ojú ẹni tí kò gbọ́n, tí kò sì ṣeé mú lọ́rẹ̀ẹ́ làwọn èèyàn fi máa ń wo ẹni tó máa ń bá èèyàn tage. Ó máa ń ṣe mí bíi pé ojú lásán ni gbogbo ohun tẹ́ni náà ń ṣe, pé ó lóhun tó ń wá.”​—Jeremy.

  Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”​—1 Kọ́ríńtì 13:​4, 5.

  Rò ó wò ná: Irú ọ̀rọ̀ wo lo lè máa sọ àbí irú ìwà wo lo lè máa hù tó lè mú káwọn èèyàn sọ ẹ́ lórúkọ pé o máa ń tage?

 • Tó o bá ń bá ẹnì kan tage, ó máa pa dà dun onítọ̀hún.

  “Mi ò kí ń fẹ́ wà ní tòsí ọkùnrin tó bá ń tage. Bó ṣe máa ń rí lójú mi ni pé torí mo jẹ́ obìnrin ló ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀. Àwọn tó máa ń bá èèyàn tage kì í ro ti ẹlòmíì, tara wọn nìkan ni wọ́n máa ń rò.”​—Jaqueline.

  Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

  Rò ó wò ná: Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí, pé ẹnì kan ṣe ohun tó mú kó o máa rò pé ó fẹ́ kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, àmọ́ tó o wá pa dà rí i pé kò rí bó o ṣe rò? Báwo ló ṣe rí lára ẹ? Kí lo lè ṣe kíwọ náà má bàa ṣe ohun tó máa pa dà dun ẹlòmíì?

 • Tó o bá ń tage, ó máa ṣòro fún ẹ láti rí èèyàn gidi tí wàá fẹ́.

  “Èmi àti ẹni tó bá ń tage ò lè fẹ́ra wa sọ́nà rárá, débi pé a máa ṣègbéyàwó. Báwo ni mo ṣe fẹ́ mọ irú ẹni tí ọkùnrin kan jẹ́, tí màá sì fọkàn tán an tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe sí mi ò dé inú ẹ̀?”​—Olivia.

  Nínú Bíbélì, Dáfídì sọ nínu sáàmù tó kọ pé: “Àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í . . . bá wọlé.”​—Sáàmù 26:4.

  Rò ó wò ná: Irú àwọn wo ló máa ń gba ti ẹni tó ń tage? Ṣé irú èèyàn tó máa wù ẹ́ kó o fẹ́ nìyẹn?