Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?

Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?

Àwọn ohun tó yẹ kó o ronú lé lórí rèé

Ibo ni òfin ìlú tó ò ń gbé sọ pé o gbọ́dọ̀ kàwé dé? Ṣé o ti kàwé débẹ̀? Tó o bá ṣàìka ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé kó o “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga” sí, tó o fi iléèwé sílẹ̀ kó o tó kàwé débi tí òfin sọ, o di ìsáǹsá nìyẹn.—Róòmù 13:1.

Ṣé o ti kàwé dé ibi tó o fojú sùn? Àwọn ohun wo lo ń torí wọn lọ kẹ́kọ̀ọ́ níléèwé? Ṣé o mọ̀ wọ́n? Ó yẹ kí o mọ̀ wọ́n. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe lo dà bí ẹni tó wọ ọkọ̀ ojú irin láìmọ ibi tóun ń lọ. Nítorí náà, fara balẹ̀ jíròrò abala “ Àwọn Àfojúsùn Tí Mo Ń Torí Wọn Lọ Iléèwé” tó wà nísàlẹ̀ yìí pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Tó o bá fi iléèwé sílẹ̀ kó o tó kàwé débi tí ìwọ àtàwọn òbí rẹ fojú sùn, ìsáǹsá ni ẹ́.

Tó o bá pa ilé ìwé tì, ṣe ló dà bí ìgbà tó o bẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin kó o tó dé ibi tó ò ń lọ

Kí ló dé tó ò fi fẹ́ lọ sí iléèwé mọ́? Lára àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó fà á ni pé o fẹ́ ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti rówó gbọ́ bùkátà tàbí pé o fẹ́ ṣiṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni. Ó sì lè jẹ́ pé o fẹ́ sá fún àwọn ìdánwò àti iṣẹ́ àṣetiléwá, tó bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ àǹfààní ti ara rẹ nìkan lò ń wá. Ohun tó le nínú ọ̀ràn yìí ni bó o ṣe máa mọ ohun tó fà á gan-an, bóyá ti ara rẹ nìkan lo ń rò tàbí àǹfààní ti àwọn ẹlòmíì. Tó bá jẹ́ torí pé o ò fẹ́ níṣòro ló ṣe fi iléèwé sílẹ̀, ibi tó o fojú sí yẹn ọ̀nà kò sí níbẹ̀ o.

Tó o bá sá fi iléèwé sílẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tó o bẹ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ ojú irin kó o tó dé ibi tó ò ń lọ. Ìnira lè wà nínú ọkọ̀ ojú irin náà, àwọn èrò inú rẹ̀ sì lè ṣòro láti bá jókòó, àmọ́ tó o bá bẹ́ kúrò nínú rẹ̀, o kò ní dé ibi tó o ń lọ, o sì lè fara pa yánnayànna. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn tó o bá sá kúrò níléèwé, ó lè túbọ̀ nira láti ríṣẹ́. Tó o bá sì ríṣẹ́, ó ṣeé ṣe kí owó tí wàá máa rí má tó èyí tó o máa rí ká ní ó kàwé de ibi tó yẹ.

Dípò tí wàá fi sá, fi sùúrù yanjú àwọn ìṣòro tó o bá pàdé níléèwé. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá ní ìfaradà tó máa mú kó rọrùn fún ẹ láti kojú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

 Àwọn Àfojúsùn Tí Mo Ń Torí Wọn Lọ Iléèwé

Iṣẹ́ pàtàkì kan tí ẹ̀kọ́ ìwé ń ṣe ni kó mú ẹ gbára dì láti rí iṣẹ́ tí wàá lè fi gbọ́ bùkátà ara rẹ àti ìdílé tó ṣeé ṣe kó o ní lọ́jọ́ iwájú. (2Tẹsalóníkà 3:10,12) Ṣé o ti pinnu irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ àti bí ohun tó o kọ́ níléèwé ṣe lè mú ẹ gbára dì fún iṣẹ́ náà? Kó o lè mọ̀ bóyá ẹ̀kọ́ tó o ń kọ́ máa wúlò fún ẹ, dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ohun wo ni mo mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa? (Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹni tó mọ báa ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn ni ẹ́? Ṣé o fẹ́ràn kó o máa ṣiṣẹ́ ọwọ́ tàbí kó o máa tún nǹkan ṣe? Ṣé o dáńgájíá nínú ká ṣàlàyé ọ̀rọ̀, ká sì yanjú ìṣòro?)

  • Irú àwọn iṣẹ́ wo ló máa jẹ́ kí ń lè ṣe àwọn nǹkan tí mo mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa?

  • Irú iṣẹ́ wo lèèyàn lè rí níbi tí mo ń gbé?

  • Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló ń mú mi gbára dì fún ìgbà tí màá bẹ̀rẹ̀ sí í wáṣẹ́?

  • Àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ wo ló máa jẹ́ kí ọwọ́ mi lè tẹ àwọn àfojúsùn mi dáadáa?

Rántí pé ìdí tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ níléèwé ni kó o lè lo ohun tó o bá kọ́ nígbà tó o ba jáde. Torí náà, má ṣe fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ kàwé, bí ẹni tó kọ̀ tí kò sọ̀ kalẹ̀ “nínú ọkọ̀ ojú irin” tó wà, ìyẹn ni pé kò fẹ́ bọ́ sípò àgbà kó máa bójú tó àwọn nǹkan.