Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ọwọ́ Wo Ló Yẹ Kí N Máa Fi Mú Òfin Táwọn Òbí Mi Bá Ṣe?

Ọwọ́ Wo Ló Yẹ Kí N Máa Fi Mú Òfin Táwọn Òbí Mi Bá Ṣe?

Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ jọ jẹ́gbẹ́ tí wọ́n lè pẹ́ níta bó ṣe wù wọ́n kí wọ́n tó wọlé, tí wọ́n lè wọ aṣọkáṣọ tí wọ́n bá fẹ́, tí wọ́n sì lè bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ síbikíbi tó bá wù wọ́n nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí wọn ò ráyè láti kíyè sí nǹkan tí wọ́n ń ṣe.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé táwọn òbí bá ń tọ́ ọmọ báyìí, àbájáde rẹ̀ kò ní dára. (Òwe 29:15) Ohun tó fà á jù lọ tí ìfẹ́ ò fi sí nínú ayé ni pé, àwọn èèyàn jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, ọ̀pọ̀ nínú wọn làwọn òbí wọn kì í ká bá wí nígbà tí wọ́n wà ní kékeré.​—2 Tímótì 3:​1-5.

Dípò kó o máa fẹ́ láti ṣe bíi tàwọn ọmọ tí wọ́n fàyè gbà láti máa ṣe ohunkóhun tó bá wù wọ́n, ronú jinlẹ̀ kó o mọ̀ pé ìfẹ́ táwọn òbí ẹ ní sí ẹ, àti ọ̀rọ̀ rẹ tó jẹ wọ́n lógún, ló mú kí wọ́n fún ẹ lófin. Tí wọ́n bá ká ẹ lọ́wọ kò láti má ṣe ṣe àwọn nǹkan kan, ṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run tó sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé:

“Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.