Dúró kó o ronú!

Ronú nípa ìrírí Rachel. Àmì A àti B ni Rachel máa ń gbà sórí káàdì rẹ̀. Àmọ́ nǹkan yí pa da nígbà tó dé ìpele keje níléèwé. Ó sọ pé “gbogbo ohun tí olùkọ́ mi lè ṣe ló ṣe kí n bàa lè fìdí rẹmi nínú ìdánwò kíláàsì rẹ̀.” Kí ló fà á? Olùkọ́ náà jẹ́ kí Rachel àti ìyá rẹ̀ mọ̀ pé òun kórìíra ẹ̀sìn wọn.

Àwọn olùkọ́ dà bí àwọn òkúta tó o lè gba orí rẹ̀ sọdá láti inú ipò àìmọ̀kan sí ẹni tó jẹ́ olóye èèyàn, àmọ́ ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ fọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ bí ìgbà tó ò ń gbé ẹsẹ̀ lé àwọn òkúta yẹn lọ́kọ̀ọ̀kan láti sọdá

Ibo ló yọrí sí? Rachel sọ pé: “Gbogbo ìgbà tó bá ti dà bíi pé ẹ̀tanú hàn nínú máàkì tí olùkọ́ yìí fún mi ni mọ́mì mi máa ń tẹ̀ lé mi láti bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà tó ṣe, ó fi mí lọ́rùn sílẹ̀.””

Ti ìwọ náà bá ní irú ìṣòro yìí, má bẹ̀rù, sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn òbí rẹ. Láìsí àní-àní, wọ́n máa fẹ́ láti bá olùkọ́ náà sọ̀rọ̀, wọ́n sì tún lè bá àwọn aláṣẹ iléèwé yín sọ̀rọ̀ tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, kí wọ́n lè yanjú ọ̀ràn náà.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń rí irú ọ̀ràn yìí yanjú lọ́nà tó dáa. Nígbà míì, o ní láti máa fara dà á ni. (Róòmù 12:17, 18) Tanya sọ pé, “Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mi ò fẹ́ràn àwọn ọmọ tó ń kọ́ rárá. Ó sábà máa ń bú wa, á sọ pé òpònú ni wá. Tẹ́lẹ̀, ó máa ń pa mí lẹ́kún, àmọ́ nígbà tó yá, mi ò kọbi ara sí ọ̀rọ̀ àbùkù tó ń sọ mọ́. Mo gbájú mọ́ iṣẹ́ mi, mo sì gbájú mọ́ iṣẹ́ tó ń kọ́ mi. Nítorí èyí, kò fi bẹ́ẹ̀ yọ mí lẹ́nu mọ́, mo sì wà lára àwọn díẹ̀ tó máa ń rí máàkì tó dáa gbà nínú ìdánwò rẹ̀. Lẹ́yìn ọdún méjì, wọ́n lé olùkọ́ náà kúrò níbi iṣẹ́.

Òtítọ́ ibẹ̀: Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè bá olùkọ́ tó le koko lò, ẹ̀kọ́ pàtàkì tó máa wúlò fún ẹ nígbèésí ayé lo kọ́ yẹn, ní pàtàkì nígbà tó o bá bá ọ̀gá tó le koko pàdé níbi iṣẹ́. (1 Pétérù 2:18) Á tún jẹ́ kó o mọyì àwọn olùkọ́ rere tó o bá ní.