Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Sanra Jù?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Sanra Jù?

Bíbélì kọ́ wa pé ká jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà.” (1 Tímótì 3:2) Èyí kan ohun tí ò ń jẹ, bó o ṣe ń jẹun àti ìgbà tó ò ń jẹun. Torí náà, ṣé wàá gbìyànjú àwọn àbá yìí wò?

Má ṣe jẹun jù. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Julia sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, bí oúnjẹ kan ṣe yó mi tó ni mo máa ń wò tí mo bá ń jẹun, àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni mo máa ń ṣíwọ́ oúnjẹ tí mo bá rí i pé mo ti fẹ́ yó.

Má ṣe máa jẹ àwọn oúnjẹ tí kì í ṣe ara lóore. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ Peter sọ pé: “Láàárín oṣù kan péré tí mi ò mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò, kìlógíráàmù márùn-ún ni mo fi jò sí i!

Máa ṣọ́ bó o ṣe ń jẹun. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Erin sọ pé: “Mo máa ń rí i pé mi kì í pa dà lọ bu oúnjẹ sí i lẹ́yìn ti àkọ́kọ́.

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Rí i pé ò ń jẹun lákòókò! Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ebi tó máa pa ẹ́ lè jẹ́ kó o jẹun ju bó ṣe yẹ lọ.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn tó máa ń sọ pé, “Mi ò fẹ́ sanra jù” máa ń sọ bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìrísí wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sí ohun tó burú nínú bí wọ́n ṣe wà. Àmọ́, kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rí i pé ó yẹ kó o dín bó o ṣe sanra kù? Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Catherine sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti dín bó ṣe sanra kù, ó ní:

“Mo ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀ kí n tó pé ọmọ ogún ọdún, kò sì wù mí kí ń sanra bẹ́ẹ̀ rárá. Bí mo ṣe rí ò tẹ́ mi lọ́rùn, inú mi kì í sì í dùn!

“Àìmọye ìgbà ni mo máa ń jẹ oríṣi àwọn oúnjẹ kan kí n lè fọn díẹ̀, àmọ́ ṣe ni mo máa ń tóbi pa dà. Torí náà, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], mo pinnu pé mo ní láti ṣe nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ yìí! Mo fẹ́ dín bí mo ṣe sanra kù lọ́nà tó yẹ, kí n sì máa wà bẹ́ẹ̀ lọ.

“Mo ra ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó yẹ kéèyàn máa jẹ àti béèyàn ṣe lè máa ṣe eré ìmárale dáadáa, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fàwọn ohun tí mo kà sílò. Mo pinnu pé tí ohun tí mo bẹ̀rẹ̀ yìí bá fẹ́ sú mi tàbí tí mo dáwọ́ rẹ̀ dúró díẹ̀, mi ò ní jáwọ́ ńbẹ̀.

“Kí ló wà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Mi ò sanra jù mọ́! Láàárín ọdún kan, mo ti dín kùn ní ìwọ̀n kìlógíráàmù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27]. Bí mo ṣe fẹ́ wà ni mo ṣe wà báyìí láti bí ọdún méjì sẹ́yìn. Mi ò tiẹ̀ rò pé ó lè ṣeé ṣe rárá!

“Mo rò pé ohun tó jẹ́ kí n lè ṣàṣeyọrí ni pé, mi ò kàn ṣọ́ irú oúnjẹ tí mò ń jẹ, ṣe ni mo yí àwọn nǹkan tí mò ń ṣe pa dà.”​—Catherine, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].