Ṣé òfin kan wà táwọn òbí ẹ ṣe nínú ilé tí ò bá ẹ lára mu? Àpilẹ̀kọ yìí àti ìwé tó o lè kọ èrò ẹ sí tó bá a wá máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ ní pa ẹ̀.

 Ojú tó yẹ kó o máa fi wò ó

Àròsọ: Tó o bá ti kúrò nílé, o ti di ọ̀gá nìyẹn, kò sófin tó dè ẹ́ mọ́.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Kò sọ́gbọ́n tó o fẹ́ dá sí i, wàá ṣì wà lábẹ́ àṣẹ àwọn kan tó o bá kúrò nílé. Ó lè jẹ́ ọ̀gá ẹ níbi iṣẹ́ tàbí ẹni tó gbà ẹ́ sílé, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ìjọba. Danielle tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) sọ pé, “Ìyàlẹ́nu ńlá ló máa jẹ fáwọn ọ̀dọ̀ tí òfin máa ń ni lára nígbà tí wọ́n wà nílé, wọ́n á rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí báwọn ṣe rò ó nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé.”

Bíbélì sọ pé: “Jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ.” (Títù 3:1) Tó o bá ń tẹ̀ lé òfin táwọn òbí ẹ ṣe, ó máa kọ́ ẹ bó o ṣe máa kojú àwọn nǹkan míì tó o bá bá pà dé lọ́jọ́ iwájú.

Ohun tó o lè ṣe: Àǹfààní táwọn òfin yìí máa ṣe ẹ́ ni kó o máa wò. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeremy sọ́ pé: “Òfin táwọn òbí mi ṣe ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ bí màá ṣe yan àwọn tó máa jẹ́ ọ̀rẹ́ mi àti bí màá ṣe máa lo àkókò mi. Kò tún jẹ́ kí n máa fi àkókó ṣòfò nídìí tẹlifíṣọ̀n, kí n sì máa jókòó ti géèmù ṣáá. Mò ń ráyè ṣe àwọn ohun tó n gbádùn mọ́ mi, tó sì ní láárí.”

 Ohun tó yẹ kó o ṣe

Àmọ́ tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òfin kan ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tamara sọ pé: “Nígbà kan, àwọn òbí mi gbà mí láyè láti rìnrìn àjò lọ́ sórílẹ̀-èdè míì. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti pa dà sílé, wọn ò tiẹ̀ jẹ́ kí n gbé mọ́tò lọ sílùú kejì tó wà ní tòsí wa, ibi tó jẹ́ pé àti wa mọ́tò débẹ̀ ò ju ogún ìṣẹ́jú lọ!”

Ká sọ pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tamara yìí ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ṣó burú kó o bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà? Kò sóhun tó burú níbẹ̀ rárá. Ìgbà tó o bá wọn sọ ọ́ àti bó o ṣe bá wọn sọ ọ́ ló ṣe pàtàkì.

Ìgbà tó o bá wọn sọ ọ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Amanda sọ pé: “O gbọ́dọ̀ ti máa hùwà tó dáa, káwọn òbí ẹ̀ sì ti gbẹ̀rí ẹ jẹ́ kí ẹnu ẹ tó lè gbọ̀rọ̀ láti sọ fáwọn òbí ẹ pé kí wọ́n ṣàtúnṣe sí òfin kan.”

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Daria gbà pé òótọ́ lohun tí Amanda sọ. Ó sọ pé, “Ìgbà tí mọ́mì rí i pé mo ti ń gbọ́ràn sáwọn lẹ́nu dáadáa ni wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àti fagi lé àwọn òfin kan.” Má gbàgbé pé o ò lè fipá mú káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ, ohun tó o bá ń ṣe ló máa mú kí wọ́n fọkàn tán ẹ.

Tó ò bá tẹ̀ lé àwọn òfin táwọn òbí ẹ ṣe nínú ilé, nǹkan ò ní lọ bó ṣe yẹ. Ṣe ló máa dà bí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ táwọn tó ń wakọ̀ òfuurufú ò bá tẹ̀ lé òfin ìrìnnà

Bíbélì sọ pé: “Pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 6:20) Tó o bá fi ohun ti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn sọ sílò, wàá lè mú káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ̀, á sì rọrùn fún ẹ láti bá wọn sọ̀rọ̀.

Bó o ṣe bá wọn sọ ọ́: Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé, “Téèyàn bá fẹ́ bá òbí ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó máa ń dáa gan-an kéèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, kó sì fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún wọn dípò kó máa jágbe mọ́ wọn tàbí kó máa ráhùn.”

Daria tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kàn fara mọ́ ohun tí Steven sọ, ó ní: “Tí mo bá tiẹ̀ ń bá mọ́mì mi jiyàn, kì í ran nǹkan. Ìgbà yẹn gan-an ni wọ́n tún wá lè mú káwọn òfin yẹn le sí i.”

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” (Òwe 29:11) Téèyàn bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń pa nǹkan mọ́ra, inú ilé nìkan kọ́ ló ti máa ṣe é láǹfààní, á ràn án lọ́wọ́ níléèwé, níbí iṣẹ́, ní gbogbo ọ̀nà.

Ohun tó o le ṣe: Máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Téèyàn ò bá lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ra, tó wá da ìbínú bọlẹ̀, ó lè ba orúkọ rere tó ti ní tẹ́lẹ̀ pé ó jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀.”— Òwe 14:29.

Ìmọ̀ràn: Fi ìwé tó o lè kọ èrò ẹ sí tó bá àpilẹ̀kọ yìí wá ṣàyẹ̀wò òfin táwọn òbí ẹ ṣe, kó o sì ronú lé e lórí. Tó bá sì pọn dandan, ìwọ àtàwọn òbí ẹ lè jọ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí.