Ìbéèrè nípa àwọn eré orí kọ̀ǹpútà

Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti ń fi géèmù orí kọ̀ǹpútà pa owó gọbọi . . .

 1. Kí ni ìpíndọ́gba ọjọ́ orí àwọn tó máa ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà?

  1. 18

  2. 30

 2. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin mélòó ló máa ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà?

  1. Nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn, márùndínlọ́gọ́ta [55] jẹ́ ọkùnrin; márùndínláàádọ́ta [45] jẹ́ obìnrin

  2. Nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] jẹ́ ọkùnrin; márùndínláàádọ́rùn-ún [85] jẹ́ obìnrin

 3. Àwọn wo ló pọ̀ jù tí wọ́n ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà?

  1. Àwọn obìnrin tó jẹ́ ọdún méjìdínlógún [18] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ

  2. Àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tàbí kí wọ́n má tó bẹ́ẹ̀

Ìdáhùn (níbàámu pẹ̀lú ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ọdún 2013):

 1. B. 30.

 2. A. Nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn, àwọn obìnrin márùndínláàádọ́ta [45] ló ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì iye àwọn tó ń gbá a lápapọ̀.

 3. A. Nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn, àwọn obìnrin mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ méjìdínlógún [18] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà, iye àwọn ọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn tó ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń gbá géèmù sì jẹ́ mọ́kàndínlógún [19].

Ìṣirò yìí lè jẹ́ kó o mọ àwọn tó máa ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà. Àmọ́, kò sọ àwọn àǹfààní tí géèmù orí kọ̀ǹpútà lè ṣe ẹ́ àti àkóbá tó lè ṣe fún ẹ.

 Àǹfààní tó lè ṣe ẹ́

Èwo lo fara mọ́ nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí táwọn èèyàn sọ nípa géèmù orí kọ̀ǹpútà?

 • “Èèyàn lè gbá géèmù pẹ̀lú ìdílé ẹni àtàwọn ọ̀rẹ́. Ọ̀nà kan ló jẹ́ láti wà pa pọ̀ pẹ̀lú wọn.”—Irene.

 • “Géèmù máa ń gbọ́kàn mi kúrò níbi ohun tí mò ń rò.”—Annette.

 • “Wọ́n máa ń mú kéèyàn já fáfá.”—Christopher.

 • “Wọ́n máa ń mú kéèyàn mọ bó ṣe lè yanjú ìṣòro.”—Amy.

 • “Wọ́n máa ń mú kéèyàn lo ọpọlọ rẹ dáadáa; wọ́n máa ń mú kéèyàn ronú, kó múra sílẹ̀, kó sì gbé ìgbésẹ̀.”—Anthony.

 • “Àwọn géèmù kan máa ń mú kéèyàn lè ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́.”—Thomas.

 • “Àwọn géèmù kan máa jẹ́ kó o fara ṣiṣẹ́, ó sì ń jẹ́ kára le.”—Jael.

Ṣé o fara mọ ohun táwọn kan sọ lókè yìí—àbí gbogbo rẹ̀ lo tiẹ̀ fara mọ́? Àǹfààní tó wà nínú àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà ni pé ó mú kí ìlera rẹ dáa sí i, kí ọpọlọ rẹ sì tún jí pépé sí i. Kódà tó bá jẹ́ pé eré ọwọ́ lásán léèyàn ń fi àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà kan ṣe, tó sì mú kéèyàn ‘gbọ́kàn kúrò níbi ohun tó ń rò’ bí Annette ṣe sọ, kì í ṣe pé ó burú náà.

● Bíbélì sọ pé àkókò wà “fún iṣẹ́ gbogbo lábẹ́ ọ̀run,” títí kan eré ìdárayá.—Oníwàásù 3:1-4, Bíbélì Mímọ́.

 Àkóbá tó lè ṣe fún ẹ

Ṣé àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà ń gba àkókò rẹ?

“Tí mo bá ti bẹ̀rẹ̀ sí i gbá géèmù báyìí, mi kì í lè dáwọ́ dúró. Màá wá máa sọ nínú ara mi pé, ‘Mo kàn fẹ́ gbá díẹ̀ sí i ni!’ Kí n tó mọ̀, ọ̀pọ̀ wákàtí ti kọjá mọ́ mi lára, mo sì ti lo àkókò tó pọ̀ jù níwájú kọ̀ǹpútà!”—Annette.

“Géèmù orí kọ̀ǹpútà máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Lẹ́yìn tó o ti ń gbá a fún ọ̀pọ̀ wákàtí, wàá máa rò pé o ti ṣe nǹkan pàtàkì kan torí o ti borí nínú géèmù márùn-ún tó o gbá, àmọ́ ká sòótọ́, o ò tí ì gbé nǹkan gidi kankan ṣe.”—Serena.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Tí o bá sọ owó nù, o lè pa dà rí i. Àmọ́, tó o bá fi àkókò ṣòfò, o ò lè rí i mọ́. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àkókò ṣe pàtàkì ju owó lọ. Torí náà, má fi àkókò ẹ ṣòfò!

● Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n . . . , kí ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.”—Kólósè 4:5.

Ṣé àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà kò tíì máa nípa lórí bó o ṣe ń ronú?

“Nínú àwọn géèmù kan, ìwà ọ̀daràn tó lè rán èèyàn lọ sẹ́wọ̀n tàbí tó lè mú kí wọ́n dájọ́ ikú fún ẹnì kan lèèyàn máa ‘ń hù’ láì tiẹ̀ kábàámọ̀ rárá.”—Seth.

“Nínú àwọn géèmù míì, àfi kẹ́ni tó ń gbá a ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ kó tó lè borí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó gba pé kí ẹni náà pa wọn nípakúpa.”—Annette.

“Nígbà míì, ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ bí ẹ ṣe jọ ń gbá géèmù lè yà ẹ́ lẹ́nu—àwọn ọ̀rọ̀ bíi ‘Kú danù!’ tàbí ‘Èmi ni màá pa ẹ́!’ ”—Nathan.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Yẹra fún àwọn géèmù tó ní àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra, irú bí ìwà ipá, ìṣekúṣe àti ìbẹ́mìílò.—Gálátíà 5:19-21; Éfésù 5:10; 1 Jòhánù 2:15, 16.

● Bíbélì sọ pé Jèhófà “kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá”, kì í ṣe ẹni tó ń hùwà ipá nìkan. (Sáàmù 11:5) Kódà, tí géèmù tó ò ń gbá ò bá tiẹ̀ sọ irú ẹni tí wàá dà lẹ́yìnwá ọ̀la, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó o jẹ́ báyìí.

Rò ó wò ná: Ìwé náà Getting to Calm sọ pé: “Àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n tí ń hùwà ipá sábà máa ń nípa tó pọ̀ lórí ìwà àwọn tó ń gbá a. Kò dà bíi tẹlifíṣọ̀n, torí kì í ṣe pé àwọn ọmọ kàn ń wo akọni kan tó ń pa àwọn èèyàn nípakúpa, àwọn fúnra wọn gan-an ni akọni. Torí pé gbígbá géèmù jẹ́ ara ọ̀nà téèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́, ìwà ipá ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn tó ń gbá a.”—Fi wé Aísáyà 2:4.

 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tí wọ́n bá ń gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà. Gbọ́ ohun táwọn méjì sọ.

“Tẹ́lẹ̀, mo máa ń gbá géèmù títí ilẹ̀ fi máa ṣú ni, màá wá máa rò pé: ‘Ṣebí oorun wákàtí márùn-un péré ni mo nílò, àbí? Jẹ́ kí n gbá díẹ̀ sí i.’ Àmọ́ ní báyìí, mo ti kọ́ bí mi ò ṣe ní jẹ́ kí géèmù tí mò ń gbá máa dí àwọn nǹkan míì lọ́wọ́. Eré tí mo lè ṣe lóòrèkóòrè tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀ ni mo kà á sí. Àmọ́ gbogbo nǹkan ni kò yẹ kéèyàn ti àṣejù bọ̀.”—Joseph.

“Mo dín àkókò tí mò ń lò nídìí géèmù kù, mo wá ráyè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan! Mo ti sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, mo ti lè ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ mi, kódà mo tún ti kọ́ bí a ṣe ń lo ohun èlò ìkọrin. Àìmọye nǹkan ló wà téèyàn lè fàkókò ẹ̀ ṣe láyé yìí!”—David.

● Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó dàgbà dénú ní láti jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà.” (1 Tímótì 3:2, 11) Wọ́n máa ń gbádùn eré ìdárayá àmọ́ wọ́n mọ ìgbà tó yẹ́ kí wọ́n dá a dúró, wọ́n máa ń kóra wọn níjàánu.—Éfésù 5:10.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà tí kò bá ti ní pa nǹkan míì lára. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí géèmù gba àkókò rẹ tàbí kó máà jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, dípò tí wàá fi gbájú mọ́ bí wàá ṣe borí nídìí géèmù kan, ǹjẹ́ kò ní dáa kó o tẹpá mọ́ bí wàá ṣe gbé nǹkan gidi ṣe nígbèésí ayé rẹ kó o lè ṣàṣeyọrí?