O wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ò ń wo fọ́tò táwọn ọ̀rẹ́ rẹ yà níbi àríyá kan tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Gbogbo wọn ló wà níbẹ̀, ohun tó o rí sì fi hàn pé wọ́n ń gbádùn ara wọn. Ṣùgbọ́n ẹnì kan wà tí ò sí níbẹ̀. Ìwọ sì lẹni ọ̀hún.

O wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Kí ló dé tí wọn ò pè mí síbẹ̀?’

Kó o tó mọ̀, inú ti ń bí ẹ. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n dà ẹ́ nù! Àfi bíi pé pàbó ni gbogbo akitiyan tó o ṣe kó o tó di ọ̀rẹ́ wọn já sí. Ó wá dà bíi pé o ò lẹ́nì kankan, èyí mú kó o bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí tí mi ò fi ní ọ̀rẹ́ kankan?’

 Ohun tó o lè bi ara rẹ nípa dídá wà

Òótọ́ àbí Irọ́

 1. Tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá pọ̀ gan-an, o ò lè dá wà láéláé.

 2. Tó o bá wà lórí ìkànnì àjọlò, o ò lè dá wà láéláé.

 3. Tó o bá ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ṣáá, o ò lè dá wà láéláé.

 4. Tó o bá ń ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì, o ò lè dá wà láéláé.

Irọ́ ni ìdáhùn sí gbólóhùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lókè yìí.

Kí nìdí?

 Ohun to yẹ kó o mọ̀ nípa níní ọ̀rẹ́ àti dídá wà

 • Ti pé o ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ gan-an kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

  Ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń jẹ mí lọ́kàn, àmọ́ nígbà míì, mi ò rò pé wọ́n rí tèmi rò. Tó o bá ń forí ṣe fọrùn ṣe kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè nífẹ̀ẹ́ rẹ, àmọ́ tó jọ pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ rẹ lọ́nà kan náà tàbí pé wọn ò kà ẹ́ sí, ṣe ló máa dùn ẹ́ wọra pé o ò lẹ́nì kankan rárá.”Anne.

 • Ti pé o wà lórí ìkànnì àjọlò kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

  “Ṣe làwọn kan máa ń kó ọ̀rẹ́ jọ bí ìgbà téèyàn kó bèbí jọ. Béèyàn bá tiẹ̀ fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ to ilé, ìyẹn ò ní káwọn bèbí ọ̀hún yá mọ́ ọn tàbí kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí i. Lọ́nà kan náà, tó ò bá ní nǹkan gidi ṣe pẹ̀lú àwọn tó o fi ṣọ̀rẹ́, ṣe làwọn ọ̀rẹ́ tó o ní lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa dà bí bèbí lásán.”—Elaine.

 • Ti pé ò ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù ṣáá kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

  “Nígbà míì tó o bá wà níwọ nìkan, ṣe ni wà á máa yẹ fóònù rẹ wò ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá bóyá lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ. Àmọ́ tẹ́nì kankan ò bá wá fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ẹ nírú àsìkò yìí, ó máa dùn ẹ́ gan-an!”—Serena.

 • Ti pé ò ń ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì kò túmọ̀ sí pé o ò ní dá wà láéláé.

  “Mo máa ń fáwọn ọ̀rẹ́ mi ní nǹkan lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ mo kíyè sí i pé wọn kì í ṣe bákan náà sí mi. Kì í ṣe pé mo kábàámọ̀ pé mò ń fún wọn ní nǹkan o, àmọ́ ó rí bákan lára mi pé wọn ò tiẹ̀ fìgbà kan fún èmi náà ní nǹkan.”—Richard.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun téèyàn ń rò ló máa ń mú kó ṣe é bí i pé ó dá wà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jeanette sọ pé: “Ohun tá à ń rò nínú wa lọ́hùn-ún ló ń fà á, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn ṣe sí wa.”

Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lọ́rẹ̀ẹ́ kankan tó o sì dá wà?

 Bí o ṣe lè borí ìṣòro yìí

Má fojú kéré ara rẹ.

“Téèyàn bá ń fojú kéré ara rẹ̀, ó lè mú kó má a dá wà. Tó o bá ń wo ara rẹ bíi pé o ò yẹ lẹ́ni téèyàn ń bá ṣọ̀rẹ́, á ṣòro fún ẹ láti bá àwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́, o sì lè má lọ́rẹ̀ẹ́.”—Jeanette.

Bíbélì sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Gálátíà 5:14) Tá a bá fẹ́ láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, a ò ní máa fojú kéré ara wa, àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ká máa gbéra ga o.Gálátíà 6:3, 4.

Má ro ara rẹ pin.

“Tó bá máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà, ṣe ló dà bí ìgbà tó o wà nínú irà. Bó o bá ṣe ń pẹ́ sí i nínú rẹ̀ ló ṣe máa ṣòro fún ẹ láti jáde, wà á kàn máa rì ni. Lọ́nà kan náà, tó o bá lọ jẹ́ kí bó o ṣe ń dá wà gbà ẹ́ lọ́kàn pátápátá, ńṣe làwọn èèyàn á máa sá fún ẹ, ìyẹn láá wá burú jù.”—Erin.

Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tá a bá ń ro tara wa nìkan ṣáá, a ò ní fi bẹ́ẹ̀ rí tàwọn èèyàn rò, ó sì ṣeé ṣe káwọn èèyàn máà fẹ́ bá wa ṣọ̀rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 12:15) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà: Tó bá jẹ́ pé ìwà táwọn míì ń hù sí ẹ ló ń pinnu bóyá o máa láyọ̀ tàbí o ò ní láyọ̀, o ò ní lè ṣàṣeyọrí kankan! Sísọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Wọn ò pe fóònù mi rí” tàbí pé “Wọn ò pè mí síbì kankan rí” fi hàn pé àwọn ẹlòmíì ló ń pinnu bóyá o máa láyọ̀. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé o ti gbé agbára lé wọn lọ́wọ́ báyìí?

Má kàn fi ẹnikẹ́ni ṣọ̀rẹ́.

Àwọn tó ń dá wà máa ń fẹ́ káwọn èèyàn yá mọ́ wọn, ó sì lè le lára wọn débi pé wọ́n á máa wá ọ̀rẹ́ kiri lójú méjèèjì, ẹni yòówù kó jẹ́. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣáà rí ẹni tá á rí tiwọn rò. Ó máa dáa kó o fi sọ́kàn pé àwọn míì á ṣe bí ọ̀rẹ́, àmọ́ ṣe ni wọ́n á lò ẹ́, tí wọ́n á sì pa ẹ́ tì. Háà, ìyẹn ló máa wá burú jù!”Brianne.

Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sóhun tí ẹni tébi ti fẹ́ pa kú ò lè jẹ. Lọ́nà kan náà, àwọn tó bá ń wá ọ̀rẹ́ lójú méjèèjì lè wá a débi tí kò yẹ. Wọ́n tiẹ̀ lè bọ́ sọ́wọ́ àwọn tó máa sọ wọ́n di bí wọ́n ṣe dà, wọ́n á sì rò pé kò sóhun tó burú nínú níní irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ àti pé àwọn ò lè rí ọ̀rẹ́ míì tó dáa jùyẹn lọ.

Lákòótán: Kò sẹ́ni tí kì í dá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó kàn jẹ́ pé bá a ṣe máa ń mọ̀ ọ́n lára yàtọ̀ síra ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bá a ṣe dá wà lè bà wá nínú jẹ́ gan-an nígbà míì, ó yẹ ká máa rántí pé, ohun tá à ń rò ló ń mú kó ṣe wá bí i pé a dá wà. Ohun tá à sì ń rò ló máa ń sọ bí nǹkan ṣe máa rí lára wa, àmọ́ a lágbára láti pinnu ohun tá a máa gbé sọ́kàn.

Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o má máa retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Jeanette tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé “Má rò pé gbogbo ọ̀rẹ́ tó o bá ní ló máa jẹ́ kòríkòsùn rẹ títí ayé, àmọ́ ó dájú pé wàá rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ látọkàn wá. Àbí kí ló tún kù? Ìyẹn gan-an ni ò sì ní jẹ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà ní gbogbo ìgbà.”

Ṣé o fẹ́ mọ̀ sí i? Ka Apá tá a pè ní “ Bó O Ṣe Lè Borí Ohun Tó Ń Bà Ẹ́ Lẹ́rù Láti Ní Ọ̀rẹ́.” O tún lè wa ẹ̀dà PDF abala “Ohun Tí Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ń Dá Wà.”