Ìdí tí àwọn èèyàn kan kì í fi í ṣòótọ́

Lóde òní, ó máa ń ṣe àwọn èèyàn bíi pé òtítọ́ ò lérè. Ohun táwọn kan máa ń rò ni pé:

  • ‘Tí mi ò bá parọ́ fún àwọn òbí mi, wọ́n lè fìyà jẹ mí.’

  • ‘Tí mi ò bá jíwèé wò nígbà ìdánwò yìí, mo lè gbòdo.’

  • ‘Tí mi ò bá kiní yìí, màá ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fowó pa mọ́ ni kí n tó lè rà á.’

Àwọn kan lè máa rò pé, ‘Kì í ṣe nǹkan bàbàrà. Ṣebí gbogbo èèyàn ló ń ṣe irú ẹ̀?’

Bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn ìbéèrè yẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́, ló gbà pé ó dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, ó sì nídìí tí wọ́n fi gbà bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé a máa jèrè ohun tá a bá ṣe, yálà rere tàbí búburú.

Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí irọ́ pípa ti ṣe fún àwọn èèyàn kan.

“Mo máa ń bá ọmọkùnrin kan sọ̀rọ̀ lórí fóònù, àmọ́ mo parọ́ fún mọ́mì mi pé kò rí bẹ́ẹ̀. Ó dá mọ́mì lójú pé irọ́ ni mò ń pa. Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo parọ́ fún wọn lórí ọ̀rọ̀ yẹn, ó sì wá múnú bí wọn gan-an. Fún ọ̀sẹ̀ méjì, wọn ò jẹ́ kí n lo fóònù, wọn ò sì jẹ́ kí n wo tẹlifíṣọ̀n fún oṣù kan. Látìgbà yẹn, mi ò tún parọ́ fún àwọn òbí mi mọ́!”—Anita .

Ronú nípa èyí: Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ó máa ṣe díẹ̀ kí mọ́mì Anita tó tún lè fọkàn tán an?

Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”Éfésù 4:25.

“Mo parọ́ fáwọn òbí mi nígbà kan, mo sì rò pé mo ti mú un jẹ, àfìgbà tí wọ́n ní kí n wá tún ohun tí mo sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sọ. Mi ò tiẹ̀ wá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan, torí pé irọ́ náà ni mo pa fún wọn tẹ́lẹ̀. Téèyàn bá ń sọ òótọ́ látìbẹ̀rẹ̀, irú nǹkan yẹn ò ní ṣẹlẹ̀ sí i!”—Anthony.

Ronú nípa èyí: Kí ni Anthony ò bá ti ṣe kí ohun tó ṣe é yẹn má bàa ṣẹlẹ̀?

Bíbélì sọ pé: “Ètè èké jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn tí ń fi ìṣòtítọ́ hùwà jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”Òwe 12:22.

“Mo ní ọ̀rẹ́ kan. Tó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí, ẹnu ẹ̀ dùn gan-an, ó sì máa ń bù mọ́ ọ̀rọ̀. Mo fẹ́ràn ọ̀rẹ́ mi yìí, mi ò sì kí ń fẹ́ ro nǹkan tó bá sọ jù. Àmọ́ kò rọrùn fún mi láti fọkàn tán an tàbí gba ọ̀rọ̀ ẹ̀ gbọ́.”—Yvonne.

Ronú nípa èyí: Ojú wo làwọn èèyàn á fi máa wo ọ̀rẹ́ Yvonne yìí torí bó ṣe máa ń bù mọ́ ọ̀rọ̀ tí kì í sì í sọ òótọ́?

Bíbélì sọ pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”Hébérù 13:18.

Tí ìpìlẹ̀ ilé kan bá fọ́, ògiri ilé yẹn lè má lágbára mọ́; lọ́nà kan náà, téèyàn ò bá ṣòótọ́, ó lè ba orúkọ rere tó ní jẹ́

 Ìdí tó fi dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́

Wá wo ohun rere tó lè ṣẹlẹ̀ tó o bá jẹ́ olóòótọ́.

“Owó já bọ́ lọ́wọ́ obìnrin kan tó ń lọ níwájú mi. Mo bá a mú un, mo wá dá a dúró, mo sì dá owó rẹ̀ pa dà fún un. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ mi gan-an. Ó ní: ‘O mà ṣèèyàn ò. Ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní ṣe ohun tó o ṣe yìí.’ Obìnrin yẹn mọ̀ pé ohun tó dáa ni mo ṣe, inú mi sì dùn gan-an!”—Vivian.

Ronú nípa èyí: Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe kí ìwà rere Vivian ya obìnrin náà lẹ́nu? Àǹfààní wo ni Vivian rí torí pé ó jẹ́ olóòótọ́?

Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni . . . àwọn tí ń ṣe òdodo ní gbogbo ìgbà.”Sáàmù 106:3.

“Iṣẹ́ olùtọ́jú ilé ni gbogbo ìdílé wa ń ṣe. Nígbà míì tá a bá ń tún ọ́fíìsì kan ṣe, a lè rí owó ẹyọ nílẹ̀. Gbogbo ìgbà tá a bá ti rí owó bẹ́yẹn la máa ń fi sórí tábìlì. Ọ̀gá kan fẹ́rẹ̀ẹ́ bínú sí wa, ó rò pé tiwa ti pọ̀ jù. Ó ní, ‘ Owó ẹyọ kan péré mà ni!’ Àmọ́ ṣẹ́ ẹ rí i, obìnrin yẹn fọkàn tán wa gan-an.”—Julia.

Ronú nípa èyí: Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn tó mọ Julia sí olóòótọ́ lè ṣe fún un tó bá ń wá iṣẹ́ míì, tó sì nílò àwọn tó lè jẹ́rìí sí i pé èèyàn dáadáa ni?

Bíbélì sọ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.”2 Tímótì 2:15.

“Wọ́n fún mi ní sọ̀wédowó níbi iṣẹ́, àmọ́ mo kíyè sí i pé owó iṣẹ́ ọgọ́rin (80) wákàtí ni wọ́n fún mi dípò mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64). Tí mo bá gbà á, owó máa pọ̀ nìyẹn, àmọ́ mi ò lè ṣe é. Mo sọ fún ọ̀gá tó ń bójú tó àkáǹtì, inú ẹ̀ sì dùn gan-an. Ilé iṣẹ́ náà lówó dáadáa, àmọ́ tí mo bá gba owó tó lé yẹn, á máa ṣe mí bíi pé mo jí i ni.”—Bethany.

Ronú nípa èyí: Ṣé ìyàtọ̀ kankan wà nínú kéèyàn jí nǹkan ní ilé iṣé àti kéèyàn jí nǹkan ẹnì kan?

Bíbélì sọ pé: “Oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”Òwe 3:32.