‘Àwọn náà kìí ṣí ilẹ̀kùn fún mi; kí wá nídìí tó fi yẹ kí ń ṣílẹ̀kùn fún wọn?’

‘Ṣé kò sí nǹkan míì tó ṣe pàtàkì tí mo lè rò ju kí n kàn máa sọ “ẹ jọ̀wọ́,” “ẹ ṣeé,” àti “ẹ má bínú” lọ ni?’

‘Kò sídìí tó fi yẹ kí n hùwà ọmọlúwàbí sí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi. Bàbá àti ìyá kan náà ló bí wa.’

Ǹjẹ́ o ti sọ èyíkéyìí lára àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o kò tíì mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn níwà ọmọlúwàbí!

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa ìwà ọmọlúwàbí

Ìwà ọmọlúwàbí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní àwọn ọ̀nà mẹ́ta tá a fẹ́ gbé yẹ̀wò yìí:

 1. Orúkọ rere. Ìwà tó o bá hù sí àwọn èèyàn ló máa sọ irú èèyàn tó o jẹ́, bóyá ní dáadáa tàbí búburú. Ojú ẹni tó dàgbà dénú tó sì mọ̀wàá hù ni wọ́n á fi wò ẹ́ tí o bá hùwà ọmọlúwàbí, àwọn èèyàn sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ pẹ̀lú! Bákan náà, tó o bá ní ìgbéraga, àwọn èèyàn máa gbà pé tara ẹ nìkan lo mọ̀, àwọn èèyàn kò ní fẹ gbà ẹ siṣẹ́ àti pe ọ̀pọ̀ àǹfààní ló máa fò ẹ ru. Bí Bíbélì ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló ṣe máa rí, ó sọ pé: “ìkà ènìyàn ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ẹ̀yà ara òun fúnra rẹ̀.”Òwe 11:17; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

 2. Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí tó bá kan àwọn táa fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Ẹni tó níwà ọmọlúwàbí tó sì mọ bí a ṣe ń ṣìkẹ́ ẹni làwọn èèyàn máa ń fẹ́ bá ṣọ̀rẹ́. Ó ṣe tan, ta ló máa fẹ́ yan onígbèéraga tàbí ọ̀dájú èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́?

 3. Ojú táwọn èèyàn máa fi wò ẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé “Tó o bá bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́,wàá ri pé àwọn náà ń bọ̀wọ̀ fún ẹ, kódà àwọn tó ní ìgbéraga gan-an ṣì máa fi ọ̀wọ̀ tìẹ wọ̀ ẹ́.” Àmọ́, èyí kò ní ṣeé ṣe tó o bá ní ìgbéraga. Bíbélì sọ pé: “òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín.”Mátíù 7:2.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Onírúurú èèyàn ni à ń bá pàdé lójoojúmọ́. Ìwà tó o bá hù sí wọn ló máa pinnu irú ojú tí wọ́n a fi wò ẹ àti bí wọ́n ṣe máa kà ẹ́ sí tó. Ká kúkú sọ bó ṣe rí gan-an pé ìwà ni ẹwà ọmọ ènìyàn!

 Bí o ṣe lè sunwọ̀n sí i

 1. Ṣàyẹ̀wò ara rẹ bóyá ó ni ìwà ọmọlúwàbí. Béèrè àwọn ìbéèrè yìí lọ́wọ́ ara rẹ: ‘Ṣe mo máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà? Báwo ni mo ṣe máa ń sọ “ẹ jọ̀wọ́,” “ẹ ṣeé,” àti “ẹ má bínú” sí? Ṣe mo máa ń ṣe nǹkan míì tí mo bá ń bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀—bíi kí n máa ka àtẹ̀jíṣẹ́ tó bá wọlé tàbí kí ń máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ pa dà? Ṣé mo máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi àbí mo kàn máa ń ṣe bó ṣe wù mí torí pé “bàbá àti ìyá kan náà ló bí wa”?’

  Bíbélì sọ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”Róòmù 12:10.

 2. Ní àfojúsùn. Kọ àwọn ohun mẹ́ta tí wàá fẹ́ láti ṣiṣẹ́ lé lórí sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀dọ́bìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó ń jẹ́ Allison sọ pé òun fẹ́ “jẹ́ ẹni tó ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ dípò kí òun máa ro ẹjọ́ lọ.” David tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé, òun fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí bí òun kò ṣe ní máa fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ lórí fóònù nígbà tí òun bá wà pẹ̀lú ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ òun mọ. Ó sọ pé “Ìwà ìbàjẹ́ ni, ńṣe ni mò ń sọ fún wọn pé ó sàn kí n bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ ju kí ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ.” Edward tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé òun fẹ́ siṣẹ́ lórí bí òun ṣe máa ń dá ọ̀rọ̀ mọ àwọn èèyàn lẹ́nu tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Jennifer tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé òun tí pinnu láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà. Ó sọ pé: “Tí mo bá ti kí àwọn àgbàlagbà pé ‘ẹ ǹlẹ́ o,’ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni màá tí wá bí máà ṣe kúrò lọ́dọ̀ wọn tí màá sì lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi tó jẹ́ ọ̀dọ́. Àmọ́ mo ti sapá láti túbọ̀ mọ̀ wọ́n sí i. Ó sì ti jẹ́ kí n lè túbọ̀ ní ìwà ọmọlúwàbí sí i!”

  Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”Fílípì 2:4.

 3. Ṣàkíyèsí bí o ṣe ṣe dáadáa sí. Fún oṣù kan, wo bí o ṣe lè túbọ̀ ṣe dáadáa sí i nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà rẹ. Níparí oṣù, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Ṣé ìwà ọmọlúwàbí tí mo hù túbọ̀ mú kí n jẹ́ èèyàn dáadáa si? Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà sunwọ̀n sí i?’ Máa ní àwọn àfojúsùn tuntun lóòrèkóòrè.

  Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”Lúùkù 6:31.