Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 2)

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ní Àìsàn tí Mò Ń Bá Fínra? (Apá 2)

Oríṣiríṣi àìsàn ló wà.

  • Tó o bá ti rí àwọn kan, wàá ti mọ̀ pé wọ́n ń ṣàìsàn, àmọ́ kì í hàn lójú àwọn míì, inú àgọ́ ara wọn lọ́hùn-ún ni nǹkan ti ń ṣe wọ́n.

  • Àwọn àìsàn kan wà tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló máa ń ṣèèyàn, àmọ́ àwọn míì wà tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ lèèyàn ń bá a yí.

  • Àwọn àìsàn kan ṣeé wò, òmíì kì í lọ bọ̀rọ̀ àmọ́ ó ṣeé bójú tó, àmọ́ àwọn kan kì í lọ rárá, ó sì máa ń burú sí i, ó tiẹ̀ lè gbẹ̀mí ẹni.

Oríṣiríṣi àìsàn tá a sọ̀rọ̀ wọn níbí ló ń ṣe àwọn ọ̀dọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá kà nípa àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin tó nírú ìṣòro yìí. Tó o bá ní àìsàn tó ò ń bá fínra, ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lè gbé ẹ ró.

  • GUÉNAELLE

  • ZACHARY

  • ANAÏS

  • JULIANA

GUÉNAELLE

Ohun tó máa ń ni mí lára jù ni kí n mọ nǹkan tí mo lè ṣe, àmọ́ kí n má lè ṣe é. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń wù mí ṣe, àmọ́ bí ara mi bá ṣe rí lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan ló máa ń pinnu ohun tí màá lè ṣe.

Àrùn kan ń ṣe mí nínú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ mi darí ohun tí mò ń ṣe bó ṣe yẹ, kì í sì í jẹ́ kí àwọn iṣan ara mi ṣiṣẹ́ dáadáa. Nígbà míì, àwọn ẹ̀yà ara mi lóríṣiríṣi látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀ á kàn dédé máa gbọ̀n tàbí kó daṣẹ́ sílẹ̀. Ó máa ń nira fún mi láti ṣe àwọn ohun tó yẹ kí n máa ṣe, bí ìrìn, ọ̀rọ̀ sísọ, ìwé kíkà, ìwé kíkọ, kì í sì í rọrùn fún mi láti lóye ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń bá mi sọ. Tọ́rọ̀ yìí bá dójú ẹ̀ tán, àwọn alàgbà ìjọ mi máa ń gbàdúrà fún mi. Ojú ẹsẹ̀ lara mi máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Mo mọ̀ pé Jèhófà kì í fi mí sílẹ̀ tí mo bá ní ìṣòro èyíkéyìí. Mi ò fẹ́ kí àìsàn tó ń ṣe mí dá mi lọ́wọ́ kọ́, kí n má lè fi gbogbo ayé mi sìn ín. Ohun tí mo gbájú mọ́ báyìí ni kí n máa kọ́ àwọn míì nípa ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì pé láìpẹ́ òun máa sọ ayé di párádísè, níbi tá ò ti ní jìyà mọ́.​—Ìṣípayá 21:1-4.

Ronú nípa èyí: Bíi ti Guénaelle, kí làwọn ohun tí ìwọ náà lè ṣe láti fi hàn pé o fẹ́ràn àwọn èèyàn?​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

ZACHARY

Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni mí nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé mo ti ní àrùn jẹjẹrẹ tó le gan-an nínú ọpọlọ. Àwọn dókítà sọ pé oṣù mẹ́jọ péré ló kù fún mi. Àtìgbà yẹn ni mo ti ń du ẹ̀mí mi.

Apá ibi tí àrùn yẹn ti ṣe mí nínú ọpọlọ ti jẹ́ kí ẹ̀gbẹ́ mi ọ̀tún rọ délẹ̀, ìyẹn ò sì jẹ́ kí n lè rìn. Ó wá di dandan pé kẹ́nì kan máa wà nílé kó lè máa gbé mi kiri.

Bí àrùn yẹn ṣe ń le sí i ló túbọ̀ ń nira fún mi láti sọ̀rọ̀ dáadáa. Mo ti wá yàtọ̀ pátápátá sí ti tẹ́lẹ̀, lémi tó jẹ́ pé mo fẹ́ràn láti máa ṣeré lórí omi, kí n máa gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, kí n sì máa fọwọ́ gbá bọ́ọ̀lù. Mo tún máa ń wàásù dáadáa, torí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Bóyá ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ bó ṣe rí lára mi pé mi ò lè ṣe àwọn tí mo fẹ́ràn gan-an mọ́.

Ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà 57:15 máa ń gbé mi ró torí ó máa ń jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà Ọlọ́run kì í fi àwọn ‘tí a tẹ̀ rẹ́ ní ẹ̀mí’ sílẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ mi. Bákan náà, Aísáyà 35:6 jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà ṣèlérí pé màá padà fi ẹsẹ̀ ara mi rìn, màá sì ní ìlera tó jí pépé tó máa jẹ́ kí n lè sìn ín.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe mí yìí máa ń mú kí nǹkan le fún mi nígbà míì, ó dá mi lójú pé Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Mo máa ń rẹ́ni bá sọ̀rọ̀ tí nǹkan bá tojú sú mi tàbí tí ẹ̀rù ń bà mí pé ẹ̀mí mi lè bọ́, torí ṣe ni mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. Kò sóhun tó lè yà mí kúrò nínú ìfẹ́ Jèhófà.​—Róòmù 8:39.

Zachary kú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún (18), lẹ́yìn oṣù méjì tá a fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Ó nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde tó bá sọ ayé di párádísè, ìgbàgbọ́ yẹn ò sì yẹ̀ títí tó fi kú.

Ronú nípa èyí: Bíi ti Zachary, báwo ni àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

ANAÏS

Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n bí mi ni ẹ̀jẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dà nínú ọpọlọ mi, bí gbogbo ara mi, pàápàá ẹsẹ̀ mi, ṣe daṣẹ́ sílẹ̀ nìyẹn.

Mo ti lè fi igi rìn lọ síbi tí kò jìnnà báyìí, àmọ́ kẹ̀kẹ́ arọ ni mo sábà máa ń lò. Ìgbà míì wà tí iṣan ara mi á kàn dédé le, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí n lè ṣe àwọn nǹkan kan, bíi kí n fọwọ́ kọ̀wé.

Yàtọ̀ sí pé àìsàn yìí máa ń tán mi lókun, ìtọ́jú tí mò ń gbà nílé ìwòsàn náà ò dẹrùn. Àìmọye ìgbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń lọ gbàtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn tó ń to ara, ọjọ́ sì ti pẹ́ tí mo ti wà lẹ́nu ẹ̀. Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà tí mo ṣiṣẹ́ abẹ àkọ́kọ́, mo sì tún ti ṣe lẹ́ẹ̀mẹta lẹ́yìn ìyẹn. Méjì tí mo ṣe gbẹ̀yìn nira gan-an torí oṣù mẹ́ta ni mi ò fi sí ńlé lẹ́yìn tí mo ṣe é tán kára mi lè yá dáadáa.

Igi lẹ́yìn ọgbà làwọn mọ̀lẹ́bí mi jẹ́ fún mi. Wọ́n máa ń pa mí lẹ́rìn-ín, ìyẹn ni kì í jẹ́ kí n sorí kọ́. Mọ́mì mi àti àǹtí mi pẹ̀lú ìkejì mi tá a jọ jẹ́ ìbejì máa ń múra fún mi dáadáa, torí mi ò lè dá múra. Ó máa ń ká mi lára pé mi ò lè wọ bàtà gíga. Nígbà kan, torí mo ṣáà fẹ́ wọ bàtà gíga dandan, ṣe ni mo kì í bọ ọwọ́, mo wá fi ń rákò kiri bí ọmọdé. A rín ṣégè ẹ̀rín lọ́jọ́ yẹn!

Mi kì í banú jẹ́ torí àwọn nǹkan tí ara mi tí ò yá ò jẹ́ kí n lè ṣe. Mò ń kọ́ èdè. Bí mi ò tiẹ̀ lè fi pátákó sáré kiri lórí omi, mo lè lúwẹ̀ẹ́. Mo fẹ́ràn láti máa wàásù ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn èèyàn torí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Àwọn èèyàn sì sábà máa ń tẹ́tí sí mi tí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀.

Àwọn òbí mi ti sọ fún mi tipẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe mí yìí ṣì máa lọ lọ́jọ́ kan. Àtìgbà yẹn ni mo ti ń mú kí ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Jèhófà máa lágbára sí i, mo sì ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé ó máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ gbogbo wa, títí kan tèmi. Èyí ló máa ń mú kí n lókun láti máa fara dà á.​—Ìṣípayá 21:3, 4.

Ronú nípa èyí: Bíi ti Anaïs, kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe tó ò fi ní máa banú jẹ́ torí àwọn ohun tí àìsàn tó ń ṣe ẹ́ ò jẹ́ kó o lè ṣe?

JULIANA

Àìsàn burúkú kan ń ṣe mí tó máa ń mú kí n jẹ̀rora, àìsàn yìí máa ń ba ọkàn, ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀dọ̀fóró jẹ́. Ó tiẹ̀ ti ń ba kíndìnrín mi jẹ́.

Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mí nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé mo ti ní àìsàn kan tí wọ́n ń pè ní lupus, tó máa ń ba awọ àti iṣan ara jẹ́. Àìsàn yìí máa ń mú kí n jẹ̀rora, kó máa rẹ̀ mí, ó sì máa ń jẹ́ kí ìṣesí mi dédé yí pa dà. Ó kàn máa ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan nígbà míì.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá (13), Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá wàásù nílé wa. Ó ka ìwé Aísáyà 41:10 fún mi, tí Jèhófà Ọlọ́run ti sọ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. . . . Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” Ìgbà yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́jọ báyìí, tọkàntọkàn ni mò ń sin Ọlọ́run, mo sì ti pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí àìsàn tó ń ṣe mi yìí di ọba láyé mi. Mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé Jèhófà ti fún mi ní ‘agbára tó kọjá ti ẹ̀dá’ kí n lè máa fayọ̀ fara dà á torí mo mọ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa.​—2 Kọ́ríńtì 4:7.

Ronú nípa èyí: Báwo ni Aísáyà 41:10 ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bíi ti Juliana kó o lè máa fayọ̀ fara da ìṣòro?