Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

“Tó o bá gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, àwọn èèyàn á rò pé orí ẹ ò pé tàbí pé ńṣe lo kàn jẹ́ kí àwọn òbí ẹ kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ tí ò nítumọ̀. Wọ́n á máa fojú ọmọdé wò ẹ́ tàbí kí wọ́n máa fojú agbawèrèmẹ́sìn wò ẹ́.”—Jeanette.

Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jeanette náà ló ṣe rí lára tìẹ? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà ti lè máa ṣiyèméjì nípa ìṣẹ̀dá. Ó ṣe tán kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n máa fojú ẹni tí kò dákan mọ̀ wo òun. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

 Ohun tó mú kí o má gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá

1. Tó o bá gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá àwọn èèyàn á sọ pé ò ń ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.

“Olùkọ́ mi sọ pé àwọn tí kò lè ronú jinlẹ̀, tí wọn ò sì lè ṣàlàyé bí ayé ṣe wà àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ló máa gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo.”—Maria.

Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Nǹkan tí àwọn tó gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ kò yé wọn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó gbajúmọ̀ bíi Galileo àti Newton gbà gbọ́ pé ẹlẹ́dàá kan wà. Ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yìí kò ṣèdíwọ́ fún ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ní. Bákan náà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lóde òní gbà pé ìgbàgbọ́ nínú ẹlẹ́dàá kò ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.

Gbìyànjú èyí wò: Tẹ ọ̀rọ̀ náà “ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́” tàbí “sọ ìdí tó fi gba Ọlọ́run gbọ́” (fi àmì àyọlò sí i) sínú àpótí tó o ti lè wá ọ̀rọ̀ jáde tó wà ní ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower, kó o lè ka àpẹẹrẹ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti onímọ̀ ìṣègùn tí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. Kíyè sí ohun tó mú kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kò túmọ̀ sí pé ò ń ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó o bá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. Kódà, bí o bá ṣe ń kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ni ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹlẹ́dàá á máa lágbára sí i.Róòmù 1:20.

2. Tó o bá gba ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo gbọ́, àwọn èèyàn á máa rò pé agbawèrèmẹ́sìn ni ẹ́.

“Ẹ̀fẹ̀ làwọn èèyàn ka ìgbàgbọ́ nínú ìṣẹ̀dá sí. Wọ́n ka ohun tí Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa ìṣẹ̀dá sí ìtàn lásán.”—Jasmine.

Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Àwọn èèyàn máa ń ní èrò òdì nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá. Bi àpẹẹrẹ, àwọn kan gbà pé kò tíì pẹ́ tí Ọlọ́run dá ayé tàbí pé ọjọ́ oní wákàtí mẹ́rìnlélógún mẹ́fà ni Ọlọ́run fi dá ayé. Bíbélì ò fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí.

 • Jẹ́nẹ́sísì 1:1 sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Ohun tí Bíbélì sọ yìí kò tako ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe pé ayé ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ bílíọ̀nù ọdún.

 • Ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” tí Bíbélì lò nínú Jẹ́nẹ́sísì lè túmọ̀ sí àkókò tó gùn. Kódà, nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:4, Bíbélì lo “ọjọ́” fún gbogbo ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọrun fi dá ohun gbogbo.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá bá àwọn àlàyé tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe mu.

 Ronú nípa ohun tí o gbà gbọ́

Téèyàn bá gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, ó yẹ kó lè fi “àwọn ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀” ti ohun tó gbà gbọ́ lẹ́yìn. Ó sì tún yẹ kéèyàn ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí àwọn ẹ̀rí náà. Ronú nípa èyí:

Kò sí ohun tá a rí láyé yìí tó kàn ṣàdédé wà, ó máa lẹ́ni tó ṣe é. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí a bá rí àwọn nǹkan bíi kámẹ́rà, ọkọ̀ òfuurufú tàbí ilé lá ti máa ń gbà pé ẹnì kan ló ṣe wọ́n. Ǹjẹ́ o lè ronú lórí àpẹẹrẹ yìí àti àwọn nǹkan míì bí ẹyinjú èèyàn, ẹyẹ tó ń fò lókè tàbí pílánẹ́ẹ̀tì wa?

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ sábà máa ń wo bí àwọn ohun tí Ọlọrun dá ṣe rí láti mú kí àwọn ohun tí wọ́n ṣe túbọ̀ dáa sí i, wọ́n sì máa ń fẹ́ kí àwọn èèyàn kan sáárá sí wọn torí ohun tí wọ́n ṣe. Tó bá rọrùn láti mọ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti iṣẹ́ tó ṣe, ǹjẹ́ ó wa yẹ kó nira láti mọ Ẹlẹ́dàá tó ga jù lọ àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ tí kò láfiwé?

 Àwọn ohun tó o lè fi ṣèwádìí ohun tó o gbà gbọ́

Tó o bá ń fara balẹ̀ ronú lórí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, èyí á túbọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹlẹ́dàá lágbára sí i.

Gbìyànjú èyí wò: Tẹ “ta ló ṣiṣẹ́ àrà yìí” (fi àmì àyọlò sí i) sínú àpótí tó o ti lè wá ọ̀rọ̀ jáde tó wà ní ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower. Ka èyí tó o bá fẹ́ràn lára àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! Nínú àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan, wo ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run dá tí ìwé ìròyìn náà sọ nípa rẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ kó o gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà?

Ṣe ìwádìí sí i: Ka àwọn ìwé pẹlẹbẹ tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè rí ẹ̀rí púpọ̀ sí i tó fi hàn pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo.

 • Was Life Created? (Èdè Gẹ̀ẹ́sì)

  • Ibi tó dára jù lọ ni ayé wà, gbogbo ohun tá a sì nílò ló wà níbẹ̀.—Wo ojú ìwé 4 sí 10.

  • A lè rí oríṣiríṣi àrà lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.—Wo ojú ìwé 11 sí 17.

  • Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ba ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ mu.—Wo ojú ìwé 24 sí 28.

 • The Origin of Life—Five Questions Worth Asking (èdè Gẹ̀ẹ́sì)

  • Kì í ṣe ara ohun tí kò ní ẹ̀mí ní àwa èèyàn ti jáde.—Wo ojú ìwé 4 sí 7.

  • Ara àwọn ohun alààyè díjú ju pé kó jáde látinú ohun tí kò ní ẹ̀mí.—Wo ojú ìwé 8 sí 12.

  • Àwọn ìsọfúnni tó wà nínú èròjà tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn kọjá agbára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀.—Wo ojú ìwé 13 sí 21.

  • Kì í ṣe ibi kan náà ni gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí ti ṣẹ̀ wá. Àwọn onímọ̀ nípa egungun àwọn ẹranko tí wọ́n ṣàwárí sọ pé ńṣe ni àwọn ẹranko kan ṣàdédé wà, àmọ́ wọn ò sọ bí àwọn ẹranko náà ṣe ń dàgbà.—Wo ojú ìwé 22 sí 29.

“Bí àwọn nǹkan ṣe rí, tí gbogbo rẹ̀ sì wà létòletò, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ẹranko tó fi dórí àgbáálá ayé yìí jẹ́ kí n gbà dájú pé Ọlọrun wà.”—Thomas.