Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 2: Ṣé Ó Yẹ Kó O Kàn Gbà Pé Òótọ́ ni Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n?

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 2: Ṣé Ó Yẹ Kó O Kàn Gbà Pé Òótọ́ ni Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n?

Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ Alex ń kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ nípa àwọn ohun alààyè, ó sì sọ fún wọn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n torí pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣèwádìí nípa ẹ̀, wọ́n sì ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni. Ọ̀rọ̀ yìí ṣe Alex bákan, torí ó gbà pé Ọlọ́run wà, òun ló sì dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ Alex ò fẹ́ kó jẹ́ pé èrò tiẹ̀ nìkan ló yàtọ̀ nínú kíláàsì. Ó wá ń sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé, ‘Táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ti ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, tí wọ́n sì gbà pé òótọ́ ni, kí wá ni tèmi?’

Ṣé irú nǹkan yẹn ti ṣe ẹ́ rí? Bóyá láti kékeré lo ti gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ pé: “Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ó lè wá jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ti ń gbìyànjú láti yí ẹ lérò pa dà pé ẹfolúṣọ̀n ló tọ̀nà, pé kò sí ẹlẹ́dàá kankan níbì kankan. Ṣé ó yẹ kó o gbà wọ́n gbọ́? Sé ó yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹfolúṣọ̀n?

 • Ìdí méjì tí kò fi yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n

 • Àwọn ìbéèrè tó o lè bi ara rẹ

 • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ìdí méjì tí kò fi yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n

 1. Ẹnu àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò kò lórí ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, síbẹ̀, èrò wọn ò tíì ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

  Ronú nípa èyí: Tí ẹnu àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ò bá kò lórí ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n, ṣé ó wá yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹfolúṣọ̀n?Sáàmù 10:4.

 2. Má kàn gba ohunkóhun gbọ́. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Zachary sọ pé, “Tó bá jẹ́ pé ṣe ni gbogbo nǹkan ṣàdédé wà, a jẹ́ pé ayé wa ò nítumọ̀ nìyẹn, títí kan gbogbo ohun tó wà lágbàáyé.” Òótọ́ kúkú lohun tó sọ. Àbí, ká ní òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ni, ìgbésí ayé ò ní nítumọ̀ kankan sí wa. (1 Kọ́ríńtì 15:32) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan, a lè rí ìdáhùn tó tẹ́ wa lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tó ń jẹ wá lọ́kàn nípa ìdí tá a fi wà láyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.Jeremáyà 29:11.

  Ronú nípa èyí: Tó o bá mọ̀ bóyá òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àbí ẹlẹ́dàá kan ló dá gbogbo nǹkan, ipa wo ló máa ní nígbèésí ayé ẹ?Hébérù 11:1.

Àwọn ìbéèrè tó o lè bi ara rẹ

OHUN TÁWỌN KAN SỌ: ‘Ṣe ni nǹkan ṣàdédé bú gbàù, gbogbo ohun tó wà lágbàáyé wá bẹ̀rẹ̀ sí í jáde.’

 • Tá ló mú kí nǹkan ọ̀hún bú gbàù?

 • Èwo ló bọ́gbọ́n mu nínú kí gbogbo nǹkan ṣàdédé wà àbí kó jẹ́ pé ohun kan tàbí ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ: ‘Ẹranko ló di èèyàn.’

 • Tó bá jẹ́ pé ẹranko ló di èèyàn, ká fi ìnàkí ṣe àpẹẹrẹ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwa èèyàn gbọ́n ju àwọn ìnàkí lọ fíìfíì? *

 • Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn ohun alààyè tó “kéré jù” pàápàá máa ń yà wá lẹ́nu torí wọ́n díjú gan-an? *

OHUN TÁWỌN KAN SỌ: ‘Wọ́n ti ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, wọ́n sì ti rí i pé òótọ́ ni.’

 • Ṣẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ yẹn ti ṣèwádìí fúnra ẹ̀?

 • Ṣé gbogbo èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ torí pé àwọn kan kàn sọ fún wọn pé gbogbo ẹni tí orí ẹ̀ pé ló gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n?

^ ìpínrọ̀ 18 Àwọn kan lè sọ pé torí ọpọlọ èèyàn tóbi ju ti ìnàkí lọ ló jẹ́ ká gbọ́n jù wọ́n lọ. Àmọ́ tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn ò fi lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, wo ìwé náà, The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, ojú ìwé 28.

^ ìpínrọ̀ 19 Wo ìwé náà, The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, ojú ìwé 8 sí 12.