Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Báwo Ni Mo Ṣe Fẹ́ Ṣe Gbogbo Iṣẹ́ Àṣetiléwá Yìí?

Báwo Ni Mo Ṣe Fẹ́ Ṣe Gbogbo Iṣẹ́ Àṣetiléwá Yìí?

Ohun tó o lè ṣe

Wá ibi tó o ti lè kẹ́kọ̀ọ́. Ó yẹ kó jẹ́ ibi tí wàá ti lè pọkàn pọ̀. Tó bá ṣeé ṣe, lo tábìlì. Má ṣe tan tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀.

Àkókò dà bí ẹṣin tó ń sáré gan-an, o ní láti mọ bí wàá ṣe máa fọgbọ́n darí rẹ̀

Mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Nítorí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ níléèwé ṣe pàtàkì, pinnu pé iṣé àṣetiléwá rẹ ni wàá kọ́kọ́ ṣe.

Má ṣe sún un síwájú. Ṣètò ìgbà tí wàá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ, kó o sì tẹ̀ lé ètò náà.

Mọ bó o ṣe fẹ́ ṣe é. Pinnu èyí tí wàá kọ́kọ́ ṣe, èyí tí wàá ṣe tẹ̀ lé e àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kọ wọ́n sorí bébà, pẹ̀lú ìwọ̀n àkókò tí wàá fi ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan. Fagi lé èyí tó o bá ti parí.

Máa sinmi. Tó o bá rí i pé o kò pọkàn pọ mọ́, dáwọ́ dúró kó o lè sinmi díẹ̀. Ṣùgbọ́n máà pẹ́ kó o tó pa dà sídìí iṣẹ́ àṣetiléwá náà.

Dá ara rẹ lójú. Rántí pé lọ́pọ̀ ìgbà, bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe tẹra mọ́ṣẹ́ tó ló máa pinnu bó ṣe máa ṣe dáadáa tó níléèwé, kì í ṣe bó ṣe ní làákàyè tó. (Òwe 10:4) O lè ṣàṣeyọrí níléèwé. Tó o bá tẹra mọ́ṣẹ́, wàá jèrè rẹ̀.