Ohun tó o lè ṣe

Máa ní èrò tó dáa! Má fọwọ́ ara rẹ fa àjálù nípa rírò pé o ò lè ṣe dáadáa nílè ìwé. Tí èrò burúkú bá ti wá sí ẹ lọ́kàn nípa àwọn ohun tó o lè ṣe, wá nńkan ṣe sí i kó o lè máa ní èrò tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn kan ń sọ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò mọ̀rọ̀ sọ (ó sì lè jẹ́ irọ́ ni wọ́n ń pa), ó fèsì pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:6) Pọ́ọ̀lù mọ àwọn nǹkan tóun ò lè ṣe. Àmọ́ ó tún mọ àwọn nǹkan tó mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa. Ìwọ ńkọ́? Àwọn ohun wo lo mọ̀ ọ́ ṣe dáadáa? Tí o kò bá mọ̀ wọ́n, o ò ṣe béèrè lọ́wọ́ àgbàlagbà kan tó fẹ́ràn rẹ? Irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ máa ṣe wọn lọ́nà tó já fáfá.

Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbámúṣé. Àbùjá ò sí tó o bá fẹ́ yege nílé ìwé. Bópẹ́ bóyá, wàá ní láti kẹ́kọ̀ọ́. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ yẹn lè bí ẹ nínú. Síbẹ̀, àǹfààní wà nínú ìkẹ́kọ̀ọ́. Kódà, pẹ̀lú ìsapá díẹ̀, o lè máa gbádùn rẹ̀. Àmọ́, kó o tó lè fi kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó gbámúṣé kọ́ra, o gbọ́dọ̀ ṣètò àkókò rẹ. Rántí pé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì sí ẹ. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. (Oníwàásù 3:1, 4; 11:9) Nítorí náà, wàá fẹ́ ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ fún eré ìnàjú bí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti ń ṣe. Àmọ́ Oníwàásù 11:4 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” Kí nìyẹn kọ́ wa? Má ṣe máa sún ohun tó yẹ kó o ṣe síwájú. O ò ní lè ṣe àwọn ohun tó ṣe pàtàkì. Kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀ eré. Má ṣàníyàn, wàá rí àyè fún méjèèjì!

Bí gbígbé irin eré ìdárayá ṣe lè mú kí iṣan rẹ lágbára bẹ́ẹ̀ náà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ taápọntaápọn lè mú kó o ṣe dáadáa nílé ẹ̀kọ́.