Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tí Mo Bá Lọ Dá Nìkan Wà Ńkọ́?

Tí Mo Bá Lọ Dá Nìkan Wà Ńkọ́?

Kí lo lè ṣe

1. Mọ ibi tó o lágbára sí. (2 Kọ́ríńtì 11:6) Ó dára pé kó o mọ kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ, síbẹ̀ àwọn ohun tó dára wà tó o lè ṣe fún àwọn èèyàn. Tó o bá mọ ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe, a lè mú kó o bọ́ lọ́wọ́ àìdára-ẹni-lójú kó o sì borí ìdánìkanwà. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Àwọn ìwà rere wo ni mo ní?’ Ronú nípa àwọn ẹ̀bùn tó o ní.

2. Fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíì. O lè kọ́kọ́ fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn mélòó kan. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jorge sọ pé: “Tó o bá kan bi àwọn èèyàn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún wọn tàbí tó o bá béèrè nípa iṣẹ́ wọn, á jẹ́ kó o túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa.

O lè rí ojútùú sí ìṣòro tó wà láàárín ìwọ àtàwọn ojúgbà ẹ

Àbá: Àwọn ojúgbà rẹ nìkan kọ́ ló yẹ kó o máa bá kẹ́gbẹ́. Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tó mọwọ́ ara wọn jù lọ nínú Bíbélì jẹ́ àwọn èèyàn tí ọjọ́ orí wọn jìnnà síra, irú bíi Rúùtù àti Náómì, Dáfídì àti Jónátánì, bẹ́ẹ̀ náà ni Tímótì àti Pọ́ọ̀lù. (Rúùtù 1:16, 17; 1 Sámúẹ́lì 18:1; 1 Kọ́ríńtì 4:17) Má gbàgbé pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ láàárín àwọn méjì kì í ṣe ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan ń dá sọ. Àwọn èèyàn máa ń mọyì ẹni tó máa ń fetí sílẹ̀ gbọ́ ọrọ̀. Nítorí náà, tó o bá jẹ́ ẹni tó ń tijú, rántí pé kò yẹ kó o máa dá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà!

3. Máa ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì.(1 Pétérù 3:8) Ká tiẹ̀ sọ pé o ò ní gba ohun tí ẹlòmíì ń sọ, ní sùúrù fún un, jẹ́ kó sọ ohun tó fẹ́ sọ. Jẹ́ kí ọrọ̀ rẹ dá lé àwọn ibi tí èrò yín ti jọra. Tó o bá rí i pé o yẹ kó o sọ èrò rẹ nípa ohun tí o kò gbà, fi ọgbọ́n àti ohùn tútù sọ ọ́.

Àbá: Ọ̀nà tó o máa fẹ́ kí wọ́n gbà bá ẹ sọ̀rọ̀ ni kó o gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Kò yẹ kó o máa pariwo tàbí kó o máa fini ṣe yẹ̀yẹ́, kó o máa búni, tàbí kó o máa dẹ́bi fún àwọn èèyàn bíi pé o dáa jù wọ́n lọ. Gbogbo ìyẹn a mú káwọn èèyàn máa sá fún ẹ. Wọ́n á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ bó o bá “jẹ́ kí àsọjáde [rẹ] máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.”—Kólósè 4:6.