Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Báwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Òfin Tí Wọ́n Fún Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Báwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Òfin Tí Wọ́n Fún Mi?

Ohun tó yẹ kó o ṣe: Mọ bí wọ́n ṣe ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀

Tó o bá mọ bí wọ́n ṣe ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀, á

  • jẹ́ káwọn míì lóye ẹ.

  • jẹ́ kó o lóye ìdí tí wọn ò fi gbà kó o ṣe nǹkan tó o fẹ́.

Ṣó o rí i, tí o ò bá fẹ́ kí wọ́n máa fojú ọmọdé wò ẹ́, ó yẹ kó o mọ bí wọ́n ṣe ń báàyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀. Báwo ló ṣe lè ṣe é?

Máa kóra ẹ níjàánu. O gbọ́dọ̀ máa kóra ẹ níjàánu tó o bá fẹ́ báàyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀ dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.”—Òwe 29:11.

Kí lẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ? Má ṣàwáwí, má bá wọn yan odì, má ti ilẹ̀kùn gbàgà, má sì jansẹ̀ mọ́lẹ̀ kiri inú ilé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àfàìmọ̀ ni wọn ò ní fún ẹ lófin tó pọ̀ sí i dípò kí wọ́n fún ẹ lómìnira sí i.

Gbìyànjú láti mọ èrò àwọn òbí ẹ. Àpẹẹrẹ: Ká sọ pé àwọn òbí ẹ ń lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́ kó o lọ síbi ìkórajọ kan. Dípò kó o máa bá wọn fà á, o lè bi wọ́n pé:

“Tẹ́nì kan tó ṣeé fọkàn tán bá bá mi lọ ńkọ́?”

Síbẹ̀, àwọn òbí ẹ lè má gbà kó o lọ. Àmọ́ tó o bá mọ́ ìdí tí wọn ò fi gbà fún ẹ, á túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti sọ nǹkan táá jẹ́ kí wọ́n gbà.

Tó o bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ, ṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń dá owó tó o yá ní báńkì pa dà. Bó o bá ṣe ṣeé fọkàn tán tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á ṣe máa yá ẹ lówó tó, ìyẹn ni pé bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á ṣe túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ.

Máa ṣe ohun táá jẹ́ káwọn òbí ẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Ká sọ pé ọkùnrin kan jẹ báǹkì kan lówó. Tó bá ń dá owó yẹn pa dà déédéé, àwọn tó ni báǹkì yẹn á fọkàn tán an, wọ́n á sì lè yá a lówó nígbà míì.

Bẹ́ẹ̀ náà ló rí nínú ilé. O jẹ àwọn òbí ẹ ní gbèsè ìgbọràn tó yẹ kó o máa san. Torí náà, tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lò ń ṣàìgbọràn, kó má yà ẹ́ lẹ́nu tí wọ́n ò bá fàyè gbà ẹ́ tó ti tẹ̀lẹ́ tàbí tí wọn ò tiẹ̀ fàyè gbà ẹ́ mọ́ rárá.”

Àmọ́, tó o bá ń ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ, kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké, ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ lọ́jọ́ iwájú.