Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

Ohun tí o lè ṣe

Fọgbọ́n yan àwọn tí wàá máa bá ṣọ̀rẹ́. Bí àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ọmọ iléèwé ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe, tó o bá dá sí i, ìyẹn á túbọ̀ mú kó ṣòro fún ẹ láti gbọ́kàn ẹ kúrò lórí rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, o lè dọ́gbọ́n fibẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí o kò fi ní dà bí olódodo àṣelékè, tí ò sì ní jẹ́ kí wọ́n fi ẹ́ ṣẹ̀sín.

Ṣé wàá gba fáírọ̀ọ̀sì láyè nínú kọ̀ǹpútà rẹ? Kí ló dé tó o wá ń gba èròkérò láyè nínú ọpọlọ rẹ?

Má ṣe lọ́wọ́ sí eré ìnàjú oníṣekúṣe. Ọ̀pọ̀ eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe lónìí ló máa ń mú kára èèyàn wà lọ́nà fún ìbálòpọ̀. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún wa? Ó ní, “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Máa sá fún eré ìnàjú tó lè ru ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sókè.

Rántí èyí: Ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ kò burú. Ọlọ́run ló dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí òòfà ìfẹ́ a fi wà láàárín wọn, ohun tó sì dára ni kí tọkọtaya gbádùn ìbálópọ̀ láàárín ara wọn. Nítorí náà, tí ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ bá wá sí ẹ́ lọ́kàn tó sì le gan-an, má ṣe rò pé èèyàn burúkú ni ẹ́ tàbí pé oníṣekúṣe ni ẹ́.

Òtítọ́ ibẹ̀: Ìwọ ni wàá yan ohun tó fẹ́ máa fi ọkàn rẹ rò. O lè jẹ́ kí èrò rẹ àti ìwà rẹ mọ́ tó o ba fẹ́ bẹ́ẹ̀!