Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Tí Wọ́n Bá Sọ Pé Dandan Ni Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Ńkọ́?

Tí Wọ́n Bá Sọ Pé Dandan Ni Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Ńkọ́?

O lè béèrè pé, “Ṣé kò dáa tí n bá ní ìbálòpọ̀ ni? Ṣebí gbogbo èèyàn ló ń ṣe é?”

Dúró kó o ronú!

Òtítọ́: Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń ṣe é.

Lóòótọ́, o ti lè kà nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé, ọ̀dọ́ méjì nínú mẹ́ta lórílẹ̀-èdè yẹn ló ti ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó jáde iléèwé girama. Àmọ́ èyí fi hàn pé ọ̀dọ́ kan nínú mẹ́ta, kò tíì ní ìbálòpọ̀, iye yẹn náà sì pọ̀ díẹ̀.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń ṣe é? Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ tó ń ní ìbálòpọ̀ ti ní ọ̀kan tàbí ọ̀pọ̀ lára ìrírí burúkú yìí.

Ìdààmú ọkàn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ tó ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó sọ pé àwọn kábàámọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà.

Tó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o fi àwòrán tó rẹwà ṣe ìnusẹ̀

Àìfọkàntánni. Lẹ́yìn tí wọ́n ní ìbálòpọ̀, àwọn méjèèjì á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ló mọye ẹni tí ẹni yìí ti bá lòpọ̀?’

Ìjákulẹ̀. Ohun tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin fẹ́ ni ọkùnrin tó máa dáàbò bo àwọn dípò ọkùnrin tó máa lo àwọn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin ti ṣàkíyèsí pé àwọn kì í fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn ọmọbìnrin tó ta ara rẹ̀ lọ́pọ̀ fún àwọn.

Òtítọ́ ibẹ̀: Ara rẹ ṣeyebíye gan-an, má fi tàfàlà. Fi hàn pé o ní ìwà rere, kó o máa ṣègbọràn sófin Ọlọ́run tó sọ pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kò dára. Nígbà tó o bá ṣègbéyàwó, wàá ní ìbálòpọ̀. Wàá gbádùn rẹ̀ dáadáa láìsí ìdààmú, àbámọ̀ àti ewu tó sábà máa ń wáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.—Òwe 7:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 7:3.