Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Tí Àwọn Òbí Mi Bá Fẹ́ Kọ Ara Wọn Sílẹ̀ Ńkọ́?

Tí Àwọn Òbí Mi Bá Fẹ́ Kọ Ara Wọn Sílẹ̀ Ńkọ́?

Ohun tó o lè ṣe

Sọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù fún ẹnì kan. Jẹ́ kí àwọn òbí rẹ mọ bó ṣe ń dùn ẹ́ tó tàbí kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò mọ ohun tó o lè ṣe sí i. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣàlàyé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ fún ẹ, kí ọkàn rẹ sì lè balẹ̀ díẹ̀.

Tí àwọn òbí rẹ kò bá lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, o lè lọ fọ̀rọ̀ lọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó sún mọ́ Ọlọ́run.—Òwe 17:17.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mọ̀ dájú pé Baba rẹ ọ̀run máa tẹ́tí gbọ́ ẹ torí òun ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un ‘nítorí ó bìkítà fún ọ.’—1 Pétérù 5:7.

Ohun tí kò yẹ kó o ṣe

Ṣe ni bíborí ìbànújẹ́ tí ìkọ̀sílẹ̀ àwọn òbí rẹ fà dà bí ìgbà téèyàn kán lápá tó sì ń jinná. Ó lè dùn ẹ́ gan-an o, àmọ́ ìbànújẹ́ yẹn ṣì máa lọ

Má ṣe fi ẹnikẹ́ni sínú. Daniel tí àwọn òbí rẹ̀ fi ara wọn sílẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méje sọ pé: “Tara wọn nìkan ni àwọn òbí mi ń rò, wọn ò tiẹ̀ ro tiwa rárá, wọn ò ro àkóbá tí ohun tí wọ́n ṣe máa ṣe fún wa.

Tí Daniel ò bá jẹ́ kí ìbínú yẹn tán kó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ìpalára wo ló lè ṣe fún un?—Ojútùú: Ka Òwe 29:22.

Kí nìdí tó fi máa dáa kí Daniel dárí ji àwọn òbí rẹ̀ tó ṣe ohun tó dùn ún yìí?—Ojútùú: Ka Éfésù 4:31, 32.

Má ṣe ohun tó máa pa ẹ́ lára. Ọmọ kan tó ń jẹ́ Denny sọ pé: “Inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro nílé ìwé, mo sì fìdí rẹmi lọ́dún kan. Lẹ́yìn ìyẹn, . . . mo di oníjàngbọ̀n nínú kíláàsì wa, mo sì máa ń jà.

Kí lo rò pé Denny fẹ́ ṣe tó fi sọ ara rẹ̀ di oníjàngbọ̀n nínú kíláàsì, tó sì ń jà?

Báwo ni ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:7 ṣe lè ran àwọn èèyàn bíi Denny lọ́wọ́ láti má ṣe ohun tó máa pa wọ́n lára?

Ọgbẹ́ ọkàn máa ń pẹ́ kó tó kúrò. Àmọ́ tí nǹkan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ déédéé, ará rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀.