Ohun tó o lè ṣe

Ronú lórí èyí: Ǹjẹ́ ó lè jẹ́ pé bó o ṣe máa ń hùwà ni kò jẹ́ káwọn òbí rẹ fọkàn tán ẹ mọ́?

Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Bi ara rẹ pé, ‘Kí ni àwọn ohun tí mo ti ṣe látẹ̀yìnwá fi hàn nípa mi? Ǹjẹ́ mo máa ń sòótọ́ fún àwọn òbí mi nípa ibi tí mo lọ àti ohun tí mo ṣe?’

Yan orúkọ ẹni tó o fẹ́ ka ìtàn rẹ̀.

 Lori  Beverly

 Lori

Mo máa ń fi àwọn lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà ránṣẹ́ láṣìírí sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí mo fẹ́ràn. Nígbà tí àwọn òbí mi mọ̀, wọ́n sọ pé kí n jáwọ́ nínú ẹ̀. Mo ṣèlérí pé màá jáwọ́ nínú ẹ̀, àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀. Odindi ọdún kan la fi wà lẹ́nu ẹ̀. Tí mo bá ti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí i, àwọn òbí mi á mọ̀, màá bẹ̀ wọ́n pé mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, àmọ́ màá tún ṣe é. Mo bá a débi táwọn òbí mi ò ti lè fọkàn tán mi nípa nǹkan kan mọ́!

Kí lo rò pé ó fà á tí àwọn òbí Lori ò fi fọkàn tán an mọ́?

Ká ní ìwọ lo bí Lori ni, kí lò bá ṣe? Kí sì nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀?

Kí ni ì bá dára kí Lori ṣe lẹ́yìn táwọn òbí rẹ̀ kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro yìí?

 Beverly

Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ ìdí táwọn òbí mi ò fi fọkàn tán mi tó bá dọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni. Mo máa ń bá àwọn kan tó fi ọdún méjì jù mí lọ lára wọn tage. Mo tún máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí lórí fóònù, tá a bá sì lọ sí àpèjẹ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹlòmíì tí mo máa ń bá sọ̀rọ̀ àfi àwọn ọ̀dọ́kùnrin. Àwọn òbí mi gba fóònù mi fún oṣù kan gbáko, wọn kì í sì í jẹ́ kí ń lọ sí àwọn ibi tí mo ti lè pàdé àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà.

Ká ní ìwọ lo bí Beverly ni, kí lò bá ṣe? Kí sì nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀?

Lójú rẹ, ṣé ọ̀nà tí àwọn òbí Beverly gbà ká a lọ́wọ́ kò ti le koko jù? Kí nìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?

Kí lo rò pé Beverly lè ṣe táwọn òbí rẹ̀ á fi lè fọkàn tán an pa dà?

Bó o ṣe lè mú káwọn òbí rẹ pa dà fọkàn tán ẹ

Ohun tó o lè ṣe

Dídi ẹni tó ṣeé fọkàn tán dà bí àtẹ̀gùn tó ò ń gùn ní ṣísẹ̀ n tẹ̀ lé jálẹ̀ ìgbà ọ̀dọ́ rẹ

Àkọ́kọ́, mọ apá ibi tí wọn kò ti fọkàn tán ẹ mọ́.

 • Ṣé àkókò tí wọ́n fún ẹ kì í kọjá kó o tó wọlé?

 • Ṣé o máa ń mú ìlérí rẹ ṣe?

 • Ṣé o máa ń ṣe nǹkan lákòókò?

 • Ṣé o mọ owó ná lọ́nà tó dáa?

 • Ṣé o máa ń parí iṣẹ́ ilé rẹ?

 • Ṣé kì í ṣe pé wọn máa ń wá jí ẹ tílẹ̀ bá mọ́?

 • Ṣé yàrá rẹ máa ń wà ní mímọ́ tónítóní?

 • Ṣé o kì í parọ́?

 • Ṣé o kì í ṣe àṣejù tó o bá ń lo fóònù tàbí kọ̀ǹpútà?

 • Ṣé o máa ń gbà àṣìṣe rẹ, tí wàá sì tọrọ àforíjì?

 • Nǹkan míì

Ìkejì, ṣe ìpinnu. Máa wá bí wàá ṣe fi hàn pé o ṣeé fọkàn tán láwọn ibi tó o ti nílò àtúnṣe. Tẹ̀ lé ìtọ́ni Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé.” (Éfésù 4:22) Láìpẹ́, gbogbo èèyàn, títí kan àwọn òbí rẹ, ló máa rí i pé o ti ń yí pa dà.—1Tímótì 4:15.

Ìkẹta, bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìpinnu tó o ṣe. Dípò tí wàá fi máa ráhùn pé wọn kò fọkàn tán ẹ, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ kó o ṣe kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ.

Ìkìlọ̀: Má retí pé kí àwọn òbí rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn tán ẹ lójú ẹsẹ̀. Láìsí àní-àní, wọ́n á fẹ́ rí i dájú pé o ń ṣe àwọn ohun tó o sọ. Lo àǹfààní yìí láti fi hàn pé o ṣeé fọkàn tán. Láìpẹ́, àwọn òbí rẹ lè fọkàn tán ẹ, kí wọn sì fún ẹ lómìnira sí i. Bo ṣe rí fún Beverly tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan níyẹn. Ó sọ pé, “Ó rọrùn láti mú káwọn èèyàn má fọkàn tán ẹ jù kí wọn fọkàn tán ẹ lọ.” Ó fi kún un pé: “Wọ́n ti ń fọkàn tán mi báyìí, mo sì ń gbádùn rẹ̀!”

Òtítọ́ Ibẹ̀: Àwọn ohun tó o bá ṣe ló máa pinnu bí wọ́n a ṣe fọkàn tán ẹ tó.