Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Nìdí Tí Àwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi Rárá?

Kí Nìdí Tí Àwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi Rárá?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí:

O fẹ́ lọ síbi àpèjẹ kan, àmọ́ kò dá ẹ lójú pé àwọn òbí rẹ á jẹ́ kó o lọ. Èwo ni wàá yàn nínú àwọn ìgbésẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí?

  1.  MÁ SỌ FÚN WỌN, ṢÁÀ KÀN LỌ NÍ TÌẸ

  2.  MÁ SỌ FÚN WỌN, MÁ SÌ LỌ

  3.  SỌ FÚN ÀWỌN ÒBÍ RẸ, KÓ O WÁ GBỌ́ OHUN TÍ WỌ́N MÁA SỌ

 1. MÁ SỌ FÚN WỌN, ṢÁÀ KÀN LỌ NÍ TÌẸ

Ìdí tó o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀: O fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ rí i pé o ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù ẹ́. O fẹ́ fi hàn pé o mọ̀ ju àwọn òbí rẹ lọ tàbí pé o ò ka ọ̀rọ̀ wọn sí.—Òwe 14:18.

Ohun tó lè yọrí sí: Ohun tó o ṣe lè wú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lórí, àmọ́ wọ́n á rí ohun kan nípa rẹ, pé ẹlẹ̀tàn èèyàn ni ẹ́. Tó o bá fi lè tan àwọn òbí rẹ jẹ, á jẹ́ pé o lè tan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ jẹ pẹ̀lú. Tí àwọn òbí ẹ bá wá mọ̀, ó máa dùn wọ́n gan-an, wọ́n á sì gbà pé o ti já àwọn kulẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máà fún ẹ láyè mọ́ láti máa jáde.—Òwe 12:15.

 2. MÁ SỌ FÚN WỌN, MÁ SÌ LỌ

Ìdí tó o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀: O ronú nípa ìkésíni náà, o sì pinnu pé ohun tí wọ́n máa ṣe níbẹ̀ kò bá ìlànà tó ò ń tẹ̀ lé mu tàbí pé àwọn kan lára àwọn tó máa wà síbẹ̀ lè jẹ́ ẹgbẹ́ búburú. (1 Kọ́ríńtì 15:33; Fílípì 4:8) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè wù ẹ́ láti lọ, àmọ́ ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti sọ fún àwọn òbí rẹ.

Ohun tó lè yọrí sí: Tí o kò bá lọ nítorí pé o mọ̀ pé ó léwu, wàá lè fi ìgboyà ṣàlàyé ìdí tó ò fi wá fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Àmọ́ tó bá jẹ́ nítorí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti sọ fún àwọn òbí rẹ ni o ò ṣe lọ, o lè máa kárí sọ sílé, tí wàá máa rò pé ìwọ nìkan ni kì í gbádùn ara rẹ.

 3. SỌ FÚN ÀWỌN ÒBÍ RẸ, KÓ O WÁ GBỌ́ OHUN TÍ WỌ́N MÁA SỌ

Ìdí tó o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀: O gbà pé àwọn òbí rẹ láṣẹ lórí rẹ, o sì máa ń ka ọ̀rọ̀ wọn sí gan-an. (Kólósè 3:20) O nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí rẹ, o kò sì fẹ́ yọ́ jáde nílé láìsọ fún wọn torí o mọ̀ pé ó máa dùn wọ́n. (Òwe 10:1) Wàá tún láǹfààní láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún wọn.

Ohun tó lè yọrí sí: Àwọn òbí rẹ á mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, o sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Tí wọ́n bá sì rí i pé ohun tó mọ́gbọ́n dání lo fẹ́ ṣe, wọ́n lè jẹ́ kó o lọ.

Ìdí Tí Àwọn Òbí Fi Lè Sọ Pé O Ò Gbọ́dọ̀ Lọ

Bíi ti àwọn òmùwẹ̀ tó máa ń yọ ẹni tó bá rì sínú omi, àwọn òbí rẹ wà ní ipò tí wọ́n ti lè rí ewu

A lè ṣàpèjúwe ìdí kan lára rẹ̀ lọ́nà yìí: Ká sọ pé o fẹ́ lọ lúwẹ̀ẹ́ ní odò kan, ó dájú pé odò tí àwọn òmùwẹ̀ tó ń yọ ẹni tó bá rì sómi wà ni wàá fẹ́ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tó o bá wà nínú omi tó ò ń ṣeré, o lè má mọ̀ nígbà tí ewu bá ń bọ̀. Àmọ́, orí òkè téńté kan làwọn òmùwẹ̀ tó ń yọ ẹni tó bá rì sómi máa ń wà, níbi tí wọ́n ti lè tètè rí ewu tó ń bọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ àwọn òbí rẹ rí. Nítorí pé ìmọ̀ àti ìrírí tí àwọn òbí rẹ ní ju tìẹ lọ, wọ́n lè rí àwọn ewu kan tí ìwọ kò rí. Àwọn òbí rẹ dà bí àwọn òmùwẹ̀ yẹn, ní ti pé wọ́n fẹ́ kó o gbádùn ara rẹ, àmọ́ wọn ò fẹ́ kó ṣe nǹkan eléwu tí kò ní jẹ́ kó o gbádùn ayé ẹ.

Ìdí mìíràn rèé: Àwọn òbí rẹ fẹ́ dáàbò bò ẹ́. Torí pé wọ́n fẹ́ràn rẹ ni wọ́n ṣe jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan kan nígbà kan tó sì jẹ́ pé láwọn ìgbà míì, wọ́n á ní kó o má ṣe é. Tó o bá sọ fún wọn pé o fẹ́ ṣe nǹkan kan, wọ́n á bi ara wọn pé, táwọn bá jẹ́ kó o ṣe nǹkan náà, ṣé àwọn á lè fara mọ́ ohun tó bá tìdí yọ? Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti rí i pé kò ní sí ewu kankan fún ẹ ni ọkàn wọn máa tó balẹ̀ pé kó o lọ ṣe nǹkan náà.

Bó O Ṣe Lè Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Máa Fún Ẹ Láyè

Àwọn nǹkan tó o lè ṣe

Máa sọ òótọ́: Bí ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ lọ? Ṣé ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ló wù mí ni àbí torí káwọn ọ̀rẹ́ mi lè gba tèmi? Ṣé torí pé ẹnì kan tí mo gba tiẹ̀ máa wá síbẹ̀ ni?’ Lẹ́yìn náà, sọ òótọ́ fún àwọn òbí rẹ. Àwọn náà ti ṣe ọmọdé rí, wọ́n sì mọ̀ ẹ́ dáadáa. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ ìdí tó o fi ń lọ. Inú wọn á dùn sí ẹ tó o bá sọ òótọ́ fún wọn, ìwọ náà á sì jàǹfààní látinú ọgbọ́n wọn. (Òwe 7:1, 2) Àmọ́, tó o bá parọ́ fún wọn, wọn ò ní gbà ẹ́ gbọ́ mọ́, kò sì dájú pé wọ́n á fún ẹ láyè.

Mọ ìgbà tó yẹ kó o lọ tọrọ àyè: Má ṣe máa lọ yọ àwọn òbí rẹ lẹ́nu pé kí wọ́n fún ẹ láyè nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé tàbí nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn kan. Ìgbà tí ara wọn bá balẹ̀ ni kó o lọ bá wọn. Àmọ́ ṣá o, má ṣe dúró pẹ́ jù kó o tó lọ bá wọn, kó o wá máa yọ wọ́n lẹ́nu pé kí wọ́n tètè dá ẹ lóhùn. Àwọn òbí rẹ kò ní fẹ́ kánjú ṣe ìpinnu. Tó o bá tètè tọrọ àyè kó tó pẹ́ jù, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè ráyè ronú kí wọ́n tó fún ẹ lésì.

Mọ ohun tó o fẹ́ sọ: Sọ ọ̀rọ̀ tó yé èèyàn kedere. Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an fún wọn. Àwọn òbí ẹ kò ní fẹ́ gbọ́ kó o sọ pé, “Mi ò mọ̀,” pàápàá nígbà tí wọ́n bá bi ẹ́ láwọn ìbéèrè bí: “Àwọn wo lẹ jọ ń lọ?” “Ṣé àgbàlagbà kan máa wà níbẹ̀?” tàbí “Ìgbà wo lo máa pa dà wálé?”

Ìwà rẹ: Má ṣe sọ àwọn òbí rẹ di ọ̀tá. Ṣe ló yẹ kẹ́ ẹ jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Tó o bá sì rò ó dáadáa, wàá rí i pé ìyẹn ló dára. Tó o bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, o ò ní máa ta kò wọ́n, àwọn náà á sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ.

Jẹ́ kí àwọn òbí ẹ mọ̀ pé o ti gbọ́n débi tí wàá fi fara mọ́ ìpinnu wọn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa fọ̀wọ̀ ẹ wọ̀ ẹ́. Tó bá di ìgbà míì, wọ́n lè jẹ́ kó o lọ síbi tó o bá fẹ́ lọ.