Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tí Mi Ò Bá Rí Ọ̀rẹ́ Tí Ọ̀rọ̀ Wa Bára Mu Ńkọ́?

Tí Mi Ò Bá Rí Ọ̀rẹ́ Tí Ọ̀rọ̀ Wa Bára Mu Ńkọ́?

Ohun tó o lè ṣe

Àkọ́kọ́, mọ irú àwọn èèyàn tó ṣòro fún ẹ́ jù lọ láti bá ṣọ̀rẹ́.

Ọjọ́ Orí:

Mi ò lè ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú . . .

 • àwọn ojúgbà mi

 • àwọn ọ̀dọ́ tó jù mi lọ

 • àwọn àgbàlagbà

Ohun tí wọ́n ní:

Mi ò lè ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn . . .

 • tó rí fìrìgbọ̀n

 • tó lẹ́bùn àrà ọ̀tọ̀

 • tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n

Irú ẹni tí wọ́n jẹ́:

Mi ò lè ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn . . .

 • tó nígboyà

 • tó gbajúmọ̀

 • tó wà nínú ẹgbẹ́ kan

Èkejì, mú gbólóhùn kan tó fi ohun tó o máa ń ṣe hàn tó o bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn tó o sọ nípa wọn ṣáájú yẹn.

 • Mo máa ń díbọ́n pé mo nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí tàbí pé mo lè ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe.

 • Mi ò kì í sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tí èmi nífẹ̀ẹ́ sí ni mo máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

 • Mo máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́, màá sì wá bí mo ṣe máa kúrò láàárín wọn.

Ẹ̀kẹta, Má ṣe dúró dìgbà táwọn èèyàn á fi sọ fún ẹ pé kó o wá di ọ̀rẹ́ àwọn, nígbà míì ìwọ lo ní láti lọ bá wọn. (Fílípì 2:4) Báwo lo ṣe máa ṣe é?

Yan àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ lọ́rẹ̀ẹ́. Ronú nípa rẹ̀ ná: Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ojúgbà rẹ nìkan lo fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́, tó o sì wá ń ṣàròyé pé o kò lọ́rẹ̀ẹ́? Ńṣe nìyẹn á dà bí ẹni tí ebi pa kú ní ibì kan tí kò jìnnà sí odò, bẹ́ẹ̀ àwọn ẹja wà nínú odò náà tí wọ́n ń ṣeré kiri!

Mọ́mì mi sọ fún mi pé kí n gbìyànjú láti máa bá àwọn tó dàgbà jù mí lọ sọ̀rọ̀. Wọ́n sọ pé ó máa yà mí lẹ́nu láti rí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ọ̀rọ̀ wa fi bara mu. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí mọ́mì mi sọ, torí pé ní báyìí mo ti wá ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀!”—Helena, ọmọ ogún ọdún.

Kọ́ bí wọ́n ṣe ń bá èèyàn sọ̀rọ̀. Ohun tó o máa ṣe ni pé, wàá máa (1) fetí sílẹ̀, (2) béèrè ìbéèrè, àti (3) fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ ọ́ lógún.—Jákọ́bù 1:19.

Mo máa ń gbìyànjú láti fetí sílẹ̀ táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀ dípò tí èmi nìkan á máa sọ̀rọ̀. Tí mo bá sì ń sọ̀rọ̀, mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ara mi tàbí kí n máa sọ ohun tí kò dáa nípa àwọn ẹlòmíì.”—Serena, ọmọ ọdún méjìdínlógún.

Bí ẹnì kan bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, ńṣe ni mo máa ń sọ pé kó ṣàlàyé fún mi, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ẹni náà túbọ̀ bá mi sọ̀rọ̀.”—Jared ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.

Onítìjú èèyàn ni mí, torí náà àfi kí n mú ara mi lọ́ranyàn kí n tó lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Àmọ́, kó o tó lè ní ọ̀rẹ́, o ní láti jẹ́ ẹni tó lọ́yàyà. Torí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ báyìí.”—Leah, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.