Ohun Tó O Lè Ṣe

Àkọ́kọ́, mọ̀ pé ohun yòówù káwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe, ìwọ lo máa dáhùn fún ohun tó o bá ṣe.

Èkejì, mọ ohun tó fẹ́ tì ọ́ ṣe ohun tí kò dára.

Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo ni ohun yìí sábà máa ń tì mí?’ (Ṣé nígbà tí mo wà nílé ìwé ni? Ṣé nígbà tí mo wà níbi iṣẹ́ ni? Tàbí níbòmíràn?) Tó o bá mọ ìgbà tí ohun náà sábà máa ń tì ọ́, á jẹ́ kò o lè yẹra fún un pátápátá.

Nísinsìnyí, wá nǹkan kan ṣe sọ́rọ̀ náà. Ohun tó o kọ́kọ́ máa ṣe ni pé kó o yẹra fún nǹkan náà tàbí kó o kúrò láyìíká nǹkan náà pátápátá. (Àpẹẹrẹ: Tó bá ń ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yin ilé ìwé o máa ń pàdé àwọn ọmọ kíláàsì rẹ kan tí wọ́n ń fẹ́ kó o mu sìgá pẹ̀lú àwọn, o lè máa gba ọ̀nà míì kó o má bàa pàdé wọn.) Òdodo ọ̀rọ̀: “Àwọn ọ̀rẹ́” tí wọ́n ń fẹ́ kó o ṣe ohun tó burú kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ gidi.

Tí ìdẹwò bá borí rẹ̀, ńṣe lo sọ ara rẹ di ẹrú fáwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ohun gbogbo lo lè yẹra fún pátápátá. Bópẹ́ bóyá, wàá bá ohun kan tó máa fà ẹ́ mọ́ra gan-an pàdé, bóyá nígbà tí o kò retí rẹ̀. Kí lo lè ṣe?

Ohun pàtàkì ni pé kó o múra sílẹ̀!

Ṣàgbéyẹ̀wò: Jésù mọ ohun tó ń ṣe tó bá kan ọ̀rọ̀ ìwà rere. Ìpinnu rẹ̀ ni pé òun a máa ṣègbọràn sí Bàbá òun nígbà gbogbo. (Jòhánù 8:28, 29) Kókó ọ̀rọ̀ náà ni pé kó o mọ ohun tó o máa ṣe kí ìdẹwò tó dé.

Ìdánrawò. Wò ó bóyá o lè rántí ohun méjì tó máa mú kó o dènà ìdẹwò tó sábà máa ń dojú kọ ẹ, kó o sì ronú nípa ohun méjì tó o lè ṣe láti dènà rẹ̀.

Kí ló dé tó o fi máa jẹ́ kí ẹlòmíì máa da rí rẹ? Ní òye tó jinlẹ̀ kó o bàa lè ṣe ohun tó tọ́. (Kólósè 3:5) Máa gbà á ládùúrà pé kó o máa ṣe ohun tó tọ́ nìṣó.—Mátíù 6:13.