Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ọkàn Mi Ń Fà sí Ẹ̀yà Kan Náà, Àbí Ó Túmọ̀ sí Pé Abẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀ Ni Mí?

Ọkàn Mi Ń Fà sí Ẹ̀yà Kan Náà, Àbí Ó Túmọ̀ sí Pé Abẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀ Ni Mí?

Rárá o!

Òtítọ́: Lọ́pọ̀ ìgbà kí ọkàn ẹni máa fà sí ọkùnrin bíi tẹni tàbí obìnrin bíi tẹni máa ń ṣẹlẹ̀ fúngbà díẹ̀.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó ń jẹ́ Lisette nìyẹn, nígbà kan ọkàn rẹ̀ fà sí ọmọbìnrin kan. Ó sọ pé: “Nínú ìmọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tí mo kọ́ nílé ẹ̀kọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá ń dàgbà àwọn omi ara máa ń ṣe ségesège. Mo sì rò pé táwọn ọ̀dọ́ bá mọ ohun tó pọ̀ nípa bí ara wọn ṣe ń ṣiṣẹ́, wọ́n á lè lóye pé fúngbà díẹ̀ ọkàn èèyàn lè máa fà sí ọkùnrin bíi tẹni tàbí obìnrin bíi tẹni, ìyẹn kò sì sọ wọ́n di abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀.

Àwọn ọ̀dọ́ ní láti yan ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, yálà kí wọ́n fara mọ́ èrò òdì táyé ní, pé èèyàn lè firú ìbálòpọ̀ tó bá wù ú tẹ́ra ẹ̀ lọ́rùn, tàbí kí wọ́n máa fi ìlànà tí kò gba gbẹ̀rẹ́, tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣèwà hù

Ṣùgbọ́n tí ọkàn ẹni bá ń fà sí ọkùnrin bíi tẹni tàbí obìnrin bíi tẹni fúngbà tó pẹ́ ńkọ́? Ṣé kò dá bíi pé Ọlọ́run rorò tó bá sọ fún ẹni tọ́kàn rẹ̀ ń fà sí ẹ̀yà kan náà pé kó sá fún ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀?

Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ pé Ọlọ́run rorò, ó yẹ kó o mọ̀ pé irú èrò bẹ́ẹ̀ wá látinú èrò burúkú táwọn èèyàn ni pé ẹnikẹ́ni lèèyàn lè bá lòpọ̀ nígbàkigbà. Bíbélì buyì kún àwọn èèyàn nígbà tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí ọkàn wọn bá tiẹ̀ fà sí ìṣekúṣe wọ́n lè yẹra fún un kí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́.Kólósè 3:5.

Ohun tí Bíbélì sọ bọ́gbọ́n mu. Ó sọ fún àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ pé kí wọ́n ṣe ohun kan náà tí àwọn ọkùnrin àti obinrin tí ọkàn wọn fà síra wọn gbọ́dọ̀ ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àìmọye èèyàn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ló máa ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìdẹwò láti ní ìbálòpọ̀ tí kò tọ́. Ohun kan náà ni àwọn tí ọkàn wọ́n ń fà sí níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin bíi tiwọn tàbí obìnrin bíi tiwọn máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ wu Ọlọ́run lóòótọ́.Diutarónómì 30:19.