Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní

Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní

‘Báwo ni mo ṣe lè máa bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀?’ ‘Báwo ni mo ṣe lè ní ọ̀rẹ́?’ ‘Kí ló burú nínú kéèyàn kàn gbé ẹnì kan sùn?’ ‘Kí nìdí tí inú mi fi máa ń bà jẹ́ báyìí?’

Tó o bá bi ara rẹ nírú àwọn ìbéèrè yìí, mọ̀ pé àwọn ẹlòmíì náà máa ń bi ara wọn bẹ́ẹ̀. Ìdáhùn tó o máa rí sí àwọn ìbéèrè yìí lè má bára wọn mu, ó sinmi lórí ibi tó o bá wá ìdáhùn náà lọ. Ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Orí àwọn ìlànà Bíbélì la gbé àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀ kà. Wọ́n á sì ṣe ẹ́ láǹfààní. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ran àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro. Wó bó ṣe lè ran ìwọ náà lọ́wọ́!

Díẹ̀ rèé lára àwọn apá tó wà nínú ìwé náà:

  • Àjọṣe Rẹ Nínú Ìdílé

  • Irú Èèyàn Tó O Jẹ́

  • Nílé Ìwé Àtàwọn Ibòmíì

  • Ọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀, Ìwà Híhù àti Ìfẹ́

  • Àwọn Ohun Téèyàn Fi Ń Ṣe Ara Rẹ̀ Léṣe

  • Àkókò Tó O Fi Ń Gbádùn Ara Rẹ

  • Ìjọsìn Rẹ

  • Àfikún fún Àwọn Òbí

O lè wa ẹ̀dà PDF ìwé yìí jáde, tàbí kó o kọ̀wé sí ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì wa láti béèrè ẹ̀dà kan ìwé náà.